Amotekun: Ó ju ẹnu Malami lọ láti ní ètò náà kò bófin mu

Oloye Olusegun Obasanjo ati gomina Seyi Makinde n di mọra wọn Image copyright @oyostategovt

Ki oju ma ribi, ẹsẹ loogun rẹ, eyi lo mu ki gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde sare tete gba ilu Abẹokuta lọ, lati ls sepade pọ pẹlu Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin kan ti wi, abẹwo Seyi Makinde naa ko sẹyin bi ijọba apapọ se ni agbekalẹ eto alaabo Amotekun ko ba ofin ilẹ wa ọdun 1999 mu.

Deede aago meji kọja isẹju diẹ ni Makinde gunlẹ si ọgba ile iyawe-kawe Ọbasanjọ to wa nilu Abẹokuta, ti awọn mejeeji si jọ se ipade bonkẹlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina Makinde, ẹni ti Senetọ Hosea Ayoola Agboola ati oludamọran rẹ feto aabo, Fatai Owoseeni kọwọrin pẹlu rẹ, jade sita lẹyin ipade naa ni aago mẹrin aabọ.

Image copyright @seyimakinde

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa, Makinde ni ijọba apapọ ko lagbara lati kede pe ikọ Amotekun ko bofin mu.

"Ni iru orilẹede taa wa yii, emi ko ro pe o yẹ ki iru agbẹjọro agba nilẹ wa sadede dide, maa da ofin se lọwọ ara rẹ.'

"Kii se oju opo ikansira ẹni lori ayelujara ni eeyan ti n se ijọba, iha ti maa si kọ si ohun ti Malami sọ ko ba yatọ to ba jẹ pe o kọ iwe si wa lori ọrọ naa, amọ ori ayelujara nikan ni mo ti n ka iroyin ohun to sọ"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Makinde fikun pe ojuse agbẹjọro agba nilẹ wa ni lati gba aarẹ nimọran lori awọn ọrọ to nii se pẹlu ofin, amọ emi ko mọ ofin to fun Malami lagbara lati sọ iru ohun to kede yii.

Bí akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì rẹ bá ti yege sí, ní ìgbéga rẹ yóò ṣe yá sí - Makinde sọ fáwọn olùkọ̀ Oyo

Image copyright Others

Ijọba ipinlẹ Oyo, ti sọ pe, igbega lẹnu iṣẹ fun awọn olukọ yoo da le bi awọn akẹkọ ti wọn n kọ ba ṣe ṣe daadaa si ninu idanwo.

Alaga ajọ to wa fun akoso ile ẹkọ girama nipinlẹ Oyo, Tescom, Pasitọ Akinade Alamu lo sisọ loju ọrọ yii nibi ifọrọwerọ kan to waye ni ileewe Ansaru Deen, ni Saki.

O ni, omi tuntun ti ru ni ẹka eto ẹkọ nipinlẹ Oyo, nitori naa gomina Seyi Makinde ti pinnu lati maa gbe awọn olukọ ga gẹgẹ bi esi idanwo awọn akẹkọ wọn ba se dangajia si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alamu ṣalaye pe ijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ, ti yoo wo bi awọn olukọ ṣe n ṣe dede si lẹnu iṣẹ, ti yoo si ṣe ayẹsi ẹni to ba ṣe dede julọ ninu wọn.

Image copyright @seyimakinde
Àkọlé àwòrán Omi tuntun ti ru ni ẹka eto ẹkọ nipinlẹ Oyo

O ni owo oṣu awọn olukọ to ma n da awuyewuye silẹ laye ijọba ana, ti di ohun igbagbe.

Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, ifọrọwerọ naa to bẹrẹ ni Saki yoo kari gbogbo agbegbe mẹfa to wa ni ipinlẹ Oyo, o si jẹ ọna lati mu ibaṣepọ to gun rege wa laarin awọn oṣiṣẹ ati ajọ ọhun.

Ṣaaju ninu ọrọ ikinni kaabọ rẹ, alaga ajọ Tescom lẹkun Saki, Aderonke Oladoyinbo fi ẹmi imore han si ijọba ipinlẹ Oyo fun akitiyan rẹ lati mu ki eto ẹkọ gberu sii.

Lẹyin naa lo rọ awọn olukọ lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba, ki aba naa lee di mimu ṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi