Michael Oluronbi: Ẹranko tó da àṣọ èèyàn bora ní mí, mo jẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀

Pasitọ Oluronbi ati iyawo rẹ Image copyright West Midlands Police

Pasitọ kan to ba ọmọ lopọ ni ọpọ igba lẹyin to ba fun wọn ni 'omi mimọ' tan, ti salaye pe ẹmi esu lo n ba oun ja.

Awọn ọmọde meje ni Michael Oluronbi foju sun laarin ogun ọdun, to si n dẹru bawọn pe wọn yoo fidi rẹmi ninu idanwo wọn nileewe tabi ki wọn ya were, ti wọn ko ba setan lati ba oun lopọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọmọdebinrin mẹrin ni pasitọ yii ti fun loyun, ti iyawo rẹ, Juliana Oluronbi si n bawọn seto bi wọn se n sẹ oyun naa.

Koda ọkan ninu awọn ọmọbinrin naa salaye pe, oun ti sẹ oyun bii marun si mẹfa fun Pasitọ nigba ti oun wa nile ẹkọ girama.

Nibayii, ileejọ kan ni Birmingham nilẹ United Kingdom ti wa ju tọkọ-taya naa si ẹwọn lori ọpọ ẹsun ti wọn fi kan wọn eyi to ni wọn jẹbi rẹ.

Iru eeyan wo ni Pasitọ Oluronbi jẹ:

Oluronbi jẹ wolii ati akọsẹmọsẹ apoogun (Pharmacist), to si n fi ọwọ lile ati agbara nla mu awọn ọmọ ijọ rẹ, ohunkohun to ba si sọ, ni abẹ ge.

Kan ninu awọn eeyan to fori sọta lọwọ Pasitọ naa ni "Ojisẹ Ọlọrun yii buru pupọ, to si n se akoba fun aye gbogbo eeyan."

Nigba ti ọmọdekunrin kan ati ọmọdebinrin mẹfa wa ni ewe, bii ọmọ ọdun mẹjọ ni Pasitọ Oluronbi ti n lo wọn nilokulo, titi ti wọn fi di agbalagba.

Bi Pasitọ Oluronbi se bẹrẹ iwa ika rẹ:

Orilẹede Naijiria ni Pasitọ Oluronbi ti bẹrẹ isẹ Ọlọrun, ninu ijọ Kerubu ati Serafu, to si da ẹka ijọ naa silẹ ninu ile rẹ ni Birmingham.

Gẹgẹ bi wọn ti sọ fun ileẹjọ, "Iwẹ mimọ" yoo waye ninu ọkan lara yara to wa loke ile rẹ, eyi to fi n dibọn lati maa ba awọn eeyan lopọ lọna aitọ, to fi de iwa ifipabanilopọ.

Awọn ọmọde naa ni wọn kan nipa fun lati maa de amure pupa lasiko to ba n ba wọn lopọ.

Image copyright West Midlands Police

Mẹta si mẹrin ninu awọn ọmọdebinrin naa lo loyun, ti wọn si sẹ oyun fun lọpọ igba, ti awọn ọlọpa si ni eyi seese fun oluronbi lẹyin to ba fi ayederu orukọ wọn silẹ lawọn ile iwosan.

Iwa ika yii lo tẹsiwaju fun ọpọ ọdun titi ti ọkan lara awọn eeyan to n ba lopọ fi tọ awọn ọlọpa lọ, ti ọwọ si tẹ Oluronbi losu karun ọdun 2018 ni papakọ ofurufu Birmingham lasiko to fẹ sa kuro nilẹ UK.

"Ẹranko to da asọ eeyan bora ni emi Oluronbi"

Ileesẹ ọlọpa ni UK se afihan fidio kan nile ẹjọ ninu eyiti Oluronbi ti sọ fun ọkan lara awọn mọlẹbi awọn eeyan to n fipa ba lopọ pe "Ẹbi oun ni gbogbo ohun to sẹlẹ naa", to si se apejuwe ara rẹ bii ẹranko to da asọ eeyan bora.

Oluronbi, tii se ẹni ọgọta ọdun lo n gbe ni agbegbe Orchard Drive, Longbridge, Birmingham, to si rẹwọn ọdun meje he lori pe o jẹbi ẹsun biba eeyan sun lọna to lodi sofin.

Iyawo Oluronbi, tii se ẹni ọdun mejidinlọgọta lo n gbe lopopona Walker, lagbegbe Walsall, to si jẹbi ẹsun mẹta to nii se pẹlu sise onigbọwọ fun iwa ifipabanilopọ.