Wasiu Ayinde: Èmi kìí ṣe Mayegun olórin àmọ́ mo fẹ́ jẹ́ olùlàjà nílẹ̀ Yorùbá

Wasiu Ayinde Image copyright Wasiu Ayinde

Gbajugbaja olorin fuji, Wasiu Ayinde to ṣẹṣẹ jẹ oye mayegun Ilẹ Yoruba ti sọ pe, oye naa kii ṣe lati buga, ṣugbọn o jẹ lati tun ilẹ Yoruba ṣe.

Mayegun lo sọ ọrọ yii nigba to gbalejo BBC Yoruba lori eto ifọrọwerọ loju opo Facebook wa.

O ni oun kii ṣe Mayegun olorin, ṣugbọn ojuṣe oun gẹgẹ bii Mayegun ni lati ṣe iṣẹ olupẹtusaawọ ati olulaja nilẹ Yoruba.

Oluomo ṣalaye pe iṣẹ oun akọkọ gẹgẹ bii Mayegun ni lati ri pe alaafia jọba nilẹ Yoruba.

Ninu idahuin rẹ si ibeere awọn eeyan lori eto naa, Kwam 1 ni "Lati kekere ni mo ti n sapa lati ri pe Naijiria tẹsiwaju, bẹrẹ lati adugbo ti mo n gbe titi de ilẹ okeere, idi niyẹn ti mo ṣe n ba awọn oloṣelu ṣepọ, mo n bawọn sọrọ, wọn si n tẹti si imọran mi."

O ṣalaye pe, ibi ti oun ti jẹ oye naa ko ni nnkan ṣe pẹlu iṣẹ to rọ mọ oye ọhun, nitori gbogbo awọn to ṣe pataki nilẹ Yoruba lo peju sibi ifinijoye naa, leyi to tumọ si pe wọn fọwọ sii.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Kabiesi Alaafin Oyo ko dede fi mi jẹ Mayegun, ọpọ ohun ni wọn fi han mi ki wọn to fi mi jẹ Mayegun, kii si n ṣe ohun ti a ṣe ni kọrọ."

Nipa awọn iṣẹ ti yoo ṣe gẹge bii Mayegun, o ni "Ituluṣe ni mo wa fun. Mi o joye lati buga, ṣugbọn oye yii wa lati ṣi awọn eeyan leti."

Lori ọrọ ikọ Amotekun to ti di ariwo lẹyin ti ijọba apapọ ni ko ba ofin mu, o sọ pe ko sẹni to mọ ọmọ pọn bi ọlọmọ, fun idi naa, ko si eewọ ninu ka ṣọra ẹni, ṣugbọn ki ijọba fi oju ṣunukun wo ọrọ ọhun.

Àkọlé àwòrán Mi o joye lati buga, ṣugbọn oye yii wa lati ṣi awọn eeyan leti

Ni ti pe Mayegun ko lee dọbalẹ fun elomiran mọ, o ni Alaafin ko ni ki oun ma bọwọ fun awọn to yẹ lati bọwọ fun, gẹgẹ bi ọmọ Yoruba.

Mayegun pari ifọrọwerọ naa pe, ki awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye ṣe ara wọn ni oṣusu ọwọ, nitori ohun to ba n ṣe Abọyade, gbogbo Ọlọya lo n ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi