Hope Uzodinma: Gbogbo ẹyìn tí ẹ pète pọ láti jà mí lólè ẹ́tọ̀ọ́ mi, mo foríjì yín

Aworan Hope Uzodinma Image copyright Facebook/SenatorHopeUzodinma

Aaya bẹ silẹ o bẹ saare ni Gomina tuntun ipinlẹ Imo Hope Uzodinma fẹ fi ọrọ ijọba rẹ ṣe pẹlu bi o ṣe ni ki wọn fi iwe eto inawo ipinlẹ naa ranṣẹ si oun laarin ọjọ mẹrin.

Hope Uzodinma fi ọrọ yii sita lẹyin iburasipo rẹ to waye ni ilu Owerri.

Ninu aṣẹ ti o pa, o ni ki oluṣiro owo agba ipinlẹ naa fi ẹkunrẹrẹ gbogbo iwe to ni ṣe pẹlu eto inawo ipinlẹ Imo lati oṣu kaarun ọdun 2010 ranṣẹ si oun laarin ọjọ mẹrin.

Bẹẹ lo tẹsiwaju pe ki wọn dawọ duro lori sisan owo kankan jade ninu akoto ijọba ipinlẹ naa.

''Mo dupẹ lọwọ ẹka idajọ to duro sinsin lati ri i pe ẹtọ mi ko dun mi. Mo si ṣe tan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu gbogbo ọmọ ipinlẹ Imo. Gbayawu ni ilẹkun mi wa ni ṣiṣi fun gbogbo yin''

Hope bakanna sọ pe oun foriji gbogbo awọn ti o gbimọran pọ lati ja oun lole ẹtọ rẹ.

Ọrọ to sọ nipa ayẹwo iwe yii ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Bi awọn kan ti ṣe n sọ pe igbesẹ naa daa lati jẹ ki gbogbo owo ilu ṣe anfaani to yẹ fara ilu, awọn miran ni o ti yara ju lati ma tọ ọna yii eleyi to fẹ jọ wi pe yoo ṣe iwaadi awọn to ṣe ijọba ṣaaju rẹ.

Wọn ni ohun to yẹ ki o gbajumọ ni ṣiṣe iṣẹ fun idagbasoke ilu yatọ si ki o ma tọ pinpin awọn to ti ṣe ijọba ṣaaju rẹ.