Biafra at 50: Báyìí ni abúlé ṣe rí kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n kété tí ó bẹ̀rẹ̀ ...

Biafra at 50: Báyìí ni abúlé ṣe rí kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n kété tí ó bẹ̀rẹ̀ ...

Ọmọọmọ: Bawo ni igbe aye yin ṣe ri ki ogun Biafra ti ẹ n sọ yii to waye

Iya agba: Awọn eeyan Biafra ko mura silẹ de ogun rara, wọn o ni nkan ijagun kankan.

Agba ni ohun ti oju Caroline Ugo ri lasiko ogun Biafra nigba naa lọhun jẹ gẹgẹ bi ọmọde.

Ẹni ti oun funrarẹ ti wa ni iran ọmọ ọmọ bayii sọ ẹ̀dà ìtàn tó dájú gangan fún ọmọdé yìí nípa ogun Biafra.

Laarin ọdun 1967 sí 1970 ti ogun yii waye, iya agba ni ni wọn o ni ibọn wọn o si ni ọta nigba naa lọhun to tilẹ le da abo bo ẹmi awa ara ilu.

Gẹgẹ bi awọn ọmọde ṣe fẹran ibeere pupọ bẹẹ ni Miracle ṣe mọ ẹkunrẹrẹ nipa ogun Biafra latẹnu iya agba ti wọn maa n pe ni grandma.

Iya agba si sọ bi igbe aye ṣe ri labule nigba naa. "Ṣùgbọ́n kete ti ogun bẹrẹ... hmmmmn."

Gẹgẹ bi iya agba ṣe sọ ọ, kaakiri oju ofurufu lo kun fun awọn ọkọ baalu ijagun to jẹ wi pe oo ni wo ohunkohun koo to sa asala fun ẹmi rẹ lọ sinu igbo lati fori pamọ.

"Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé títí d'òní".

Ẹwẹ iya yii ni oun ti pinu o, pé kí ẹnikẹ́ni má tilẹ̀ dárúkọ ogun léti rẹ̀ láé láé.