Nigerian Soldier: Àṣìta ìbọn sọ́já pa ẹgbọn Kamsi láàrin fà kí n fà á ọ̀rọ̀

Sọja Naijiria Image copyright Getty Images

Ariwo hee sọ ni ile kan to wa ni agbegbe Seaside Estate, Badore Ajah ni ipinlẹ Eko bi ọta ibọn sọja kan ṣe ṣe eṣiṣi ba ẹgbọn arabinrin kan to pe e lati wa ba a na aladugbo rẹ.

Ileeṣẹ Ọlọpa ipinlẹ Eko ti fọrọ sita pe lootọ ni ẹmi arabinrin naa ti ọwọ sọja ti a ko mọ orukọ rẹ bọ.

Iṣẹlẹ yii waye ni agbegbe Ajah ni ipinlẹ Eko nigba ti iroyin sọ pe ẹgbọn oloogbe gan lo lọ pe sọja wa pe ko ba oun na aladugbo rẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana ti fi ọrọ lede pe Ọlọpa ipinlẹ Eko ti mọ nipa iṣẹlẹ naa.

Ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan lọjọ iṣẹgun lo ṣi aṣọ loju ọ̀rọ̀ naa.

Iroyin taa gbọ ni pe oloogbe ati ẹgbọn rẹ lo ni gbọnmi sii omi o to pẹlu aladugbo wọn kan ki ọkan lara wọn to lọ pe sọja wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTítí d'òní, Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé - Grandma Biafra

Kamsi lorukọ ẹni to lọ pe sọja. Iroyin ti a gbọ ni pe oun ati ọmọ iya rẹ fẹ ko jade ni ile ti wọn n gbe lai san gbogbo gbese owo ti wọn n jẹ ti aladugbo wọn si.

Eyi si lo mu ki Kamsi lo ẹsẹ gigun pe o mọ sọja ri lati lọ wa ba a ṣe moyo iya fun aladugbo wọn ọhun.

Ẹwẹ, nigba ti sọja naa de, ẹnu fa ki n fa a ọrọ ni sọja yii ati arakunrin to jẹ aladugbo awọn to pe e wa wa ti ọta ibọn meji fo yọ latẹnu ibọn sọja to si ta ba obinrin naa.

Nigba to ya ni wọn pe Ọlọpaa si ọrọ naa ṣugbọn sọja ti baba na papa bora ki awọn Ọlọpaa to de. Ni wọn ba ko ati Kamsi ati aladugbo rẹ lọ si agọ Ọlọpaa adugbo naa.