Ìtàn Mánigbàgbé: Bode Thomas ní ọpọlọ pípé, ó jẹ́ aṣaájú àmọ́ ó ní inú fùfù

Olabode Thomas Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Bode Thomas ní ọpọlọ pípé, ó jẹ́ aṣaájú àmọ́ ó ní inú fùfù

Orukọ Ọmọọba Alfred Olabode Akanni Thomas, ti gbogbo eeyan mọ si Olabode Thomas, lee ma nitumọ mọ niwaju awọn ọdọ iwoyi amọ arugbo rẹ ti se oge ri nilẹ yii, ekisa rẹ si ti lo igba ri.

Lootọ orukọ Olabode Thomas lee ma jẹ ki awọn eeyan ranti adugbo kan ti wọn fi sọri rẹ ni agbegbe Surulere nipinlẹ Eko, amọ ohun ribiribi to se nile aye ko gbọdọ parẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi Olabode Thomas ko tilẹ dagba tabi darugbo ko to jade laye, nitori ko lo ju ọdun mẹrinlelọgbọn lọ, to fi tẹri gbasọ, sibẹ a ko gbọdọ gbagbe akanda ọmọ Yoruba yii, tori ipa to ko si idagbasoke iran Yoruba ati Naijiria lapapọ.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Bode Thomas ní ọpọlọ pípé, ó jẹ́ aṣaájú àmọ́ ó ní inú fùfù

Gẹgẹ baa ti ri ka loju opo ikansiraẹni lori ayelujara, Wikipedia, awọn ohun to yẹ ka mọ nipa Olabode Thomas ree, tori bi onirese rẹ ko ba fingba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ ko lee parun.

Ta ni Olabode Thomas, iru igbe aye wo lo gbe?

 • Osu Kẹwaa, ọdun 1919 ni Olabode Thomas de ile aye, iyẹn lẹyin ọdun marun un ti baba Naijiria, Lord Lugard so ẹkun ariwa pọ mọ guusu, ti wọn si di Naijiria kansoso
 • Olokoowo to gbajugbaja nilu Eko ni Andrew Thomas ati iyawo rẹ ti wọn jẹ obi Bode Thomas, ilu Ọyọ Alaafin ni wọn si ti wa sisẹ aje nilu Eko.
 • Koda, a si lee ni idile ọlọla ati olowo lo ti jade, ọmọ ti wọn fi ọla ati owo tọ lati kekere ni Bode Thomas.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Yorùbá: Temidayọ Ọlọfinsawo ní kò rọrùn láti darí òṣìṣẹ́ ọlọ́pọlọ pípé
 • Bode Thomas jẹ omiran ẹda, ẹni to ga, to si ṣigbọnlẹ bẹẹ, eyi to mu ki wọn fun ni orukọ inagijẹ 'Buldozer', bẹẹ si ni kii faaye gba ijakulẹ, to si maa n wa aseyọri ninu gbogbo ohun to ba dawọle
 • Ile ẹkọ girama CMS ti Samuel Ajayi Crowther da silẹ ni Bode Thomas lọ, to si bẹrẹ isẹ lọgan to pari iwe mẹwaa rẹ bii akọwe nileesẹ Reluwe ilẹ wa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈyí ni ìtàn bí ẹni tí mó gbọ́njú mọ̀ bíi bàbà ṣe fipá bá mi lájọṣepọ̀
 • Nigba to di ọdun 1939, ni Bode Thomas morile ilu London lati lọ kọ ẹkọ nipa imọ ofin, to si di agbẹjọro, to si di ojulowo lọya lọdun 1942, ko to pada wale lati wa da ileesẹ agbẹjọro tiẹ silẹ nilu Eko
 • Bode Thomas, Frederick Rotimi William ati Remilekun Fani Kayode ni wọn dijọ da ileesẹ naa silẹ, ti wọn pe ni Thomas, Williams and Kayode law firm
 • Ọdun 1946 ni Bode Thomas di agbẹjọro fun ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa, to si tun jẹ ọkan lara awọn eeyan to da ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, taa mọ si ẹgbẹ Awolowo, Action Group silẹ

O ṣójú mí kóró bí wọ́n ṣé fí àdó olóró pa Dele Giwa lọdún 1986- Soyinka

Pius Adesanmi ní kò bá rọ́pò Wole Soyinka tí kò bá kú - ọmọ Naijiríà

Soyinka: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ayédèrú ìròyìn ti pa mí

Wole Soyinka rèé láti kékeré

 • Ọdun 1949 ni Bode Thomas gba oye Balogun Oyo, eyi to lo lati fa oju awọn Ọba, ijoye ati eeyan jankan-jankan wa sinu ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, ti ero oun ati Oloye Obafemi Awolowo si saAba maa n yatọ lasiko ti wọn ba n jiroro ninu ẹgbẹ.
 • Bode Thomas di Minisita feto igbokegbodo ọkọ labẹ ofin Mcpherson lọdun 1951, to si n soju ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ibẹ si lo ti n fọnrere fun agbekalẹ ijọba awa ara wa lorilẹ-ede yii , to fẹ ko bẹrẹ lọdun 1956
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ
 • Nigba ti wahala suyọ lori ofin Mcpherson losu kẹta, ọdun 1953 ni Bode Thomas kọwe fi ipo minisita silẹ, amọ o pada wa di minisita fun isẹ ode lẹyin ipade apapọ lori atunse ofin to waye nilu London
 • Itan fi ye wa pe bi Bode Thomas se jẹ ọlọpọlọ pipe ẹda to, naa lo ni ọkan giga to, eyi to mu ki ibasepọ oun ati awọn olori kan ma gun rara, to fi mọ Ọlọla Ahmadu Beloo ati Alaafin Adeyẹmi keji.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo itan omi gbigbona ati tutu ni Ikọgosi Ekiti
 • Bode Thomas jẹ oninu fufu ti kii pẹ binu, kii pa ọrọ mọra, o maa n sọ tinu rẹ jade lai fẹ mọ ẹniti ọrọ naa yoo bi ninu, eyi to maa n mu ko di ọta ọpọ eeyan
 • Nibi ipade igbimọ lọbalọba to waye lọdun 1953 eyi ti Bode Thomas jẹ alaga fun, la gbọ pe o ti yaju si ọba Adeniran Adeyẹmi, tii se baba Alaafin Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta to wa lori oye bayii, to si n sọrọ si ori ade naa pe ko dide duro lati yẹ oun si nigba ti oun wọle, gẹgẹ bi awọn Ọba alaye yoku to wa nikalẹ ti se
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele
 • Iroyin kan ti ko fidi mulẹ, to n lọ lati atẹnudẹnu tun sọ pe ọrọ yii bi Ọba Adeyẹmi ninu to bẹẹ, to si ni ki Bode Thomas maa gbo lọ pẹlu bo se n bu oun yii, lọjọ kejilelogun, osu Kọkanla lẹyin ipade ti Bode dele rẹ ni Yaba nilu Eko lati Ọyọ, lootọ lo ba n gbo bii aja.
 • Wọn gbe Bode Thomas lọ silu Ijẹbu Igbo fun itọju, sugbọn nibẹ lo ti tẹri gbasọ lọjọ Kẹtalelogun, osu Kọkanla, ọdun 1953
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí
 • Bode Thomas fẹ iyawo, ti orukọ rẹ n jẹ Lucretia Sobola Odunsi, to si bi ọpọ ọmọ. Lara wọn ni Ẹniọla ati Dapọ.

Ọmọọba Alfred Olabode Akanni Thomas ku togo-togo, ko gbe ile aye lati da awọn ara to wa ninu rẹ nitori ọdun mẹrinlelọgbọn pere lo se nile aye.

Èyí ni bí ogun abẹ́lé Biafra ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà

Ọ̀pọ̀ àwòrán tó ń ṣeni láàánú rèè nípa ogun abẹ́lé Nàíjíríà

Ǹjẹ́ o mọ ipa tí ẹja Panla kó lásìkò ogun abẹ́lé Biafra?

Ọta ìbọn ogun Biafra ṣì wà lọ́rùn mi lẹ́yìn àádọ́ta ọdún tí ogun parí - Umar

Awọn ẹkọ ti itan igbe aye Bode Thomas kọ wa:

 • Ẹkọ akọkọ ni pe a gbọdọ se amulo ọpọlọ ti Ọlọrun fun wa lati fi mu idagbasoke ba awujọ ati iran wa
 • Ẹkọ miran ti itan igbe aye Bode Thomas kọ wa tun ni lati mase fi aaye gba ibinu tabi sọrọ odi, paapaa si awọn eeyan to ju wa lọ.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi
 • Ikẹta ni pe a gbọdọ maa wa ọrẹ kun ọrẹ ni, kii se ka maa wa ọtọ kun ọta lẹnu isẹ abi ni ilu abinibi wa
 • Itan igbe aye Bode Thomas tun kọ wa pe ninu gbogbo ohun ti a ba n se, ka fi suuru kun nitori ibinu maa n ba nkan jẹ ni
 • O tun kọ wa pe ka maa sọ ẹnu wa, ẹnu lẹbọ tori ọrọ rere lo n fa obi lapo, ọrọ buruku si lo n fa ida lakọ.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTítí d'òní, Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé - Grandma Biafra

A wa gbadura pe Ọba oke tẹ Alfred Olabode Akanni Thomas si afẹfẹ rere nibayii to ti pe ọdun mẹtadinlaadọrin to ti jade laye.