Fire: Ọkùnrin mẹ́fà àti obìnrin mẹrin ni wọ́n rí gbé jáde nínú ọkọ̀ akérò tó jóná

Ọkọ to jona

Ọjọ buruku esu gbomi mu ni ọjọbọ oni jẹ fun awọn mọlẹbi idile to jona ninu ọkọ akero kan to jona lagbegbe Ijẹbu Ifẹ, lopopona marosẹ Ọrẹ si Ijẹbu Ode lọ si Sagamu.

Atẹjade kan ti ajọ FRSC, ẹka tipinlẹ Ogun fisita lo sisọ loju isẹlẹ yii pẹlu afikun pe deede aago mẹta kọja ogun isẹju lọsan oni ni ọkọ akero Toyota kan, ti ero mẹẹdogun wa ninu rẹ sadede gbina.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpẹlọpẹ awọn osisẹ ajọ ẹsọ oju popo FRSC ti wọn lọ sisẹ idoola ẹmi loju ẹsẹ ti isẹlẹ naa waye, amọ awọn ero kan jona ninu isẹlẹ naa, ti awọn miran si ha sinu ọkọ ọhun.

Image copyright Others

Atẹjade naa ni ọkunrin mẹfa ati obinrin mẹrin ni wọn ri gbe jade ninu ina naa, nigba ti ọkunrin meji ati obinrin kan ti jona kọja ala, nigba tawọn osisẹ panapana yoo fi de ibi isẹlẹ naa.

Iwadi fihan pe ọkọ akero to jẹ tileesẹ ọlọkọ ero De-Modern Transport Company, to n bọ lati apa ila oorun ilẹ yii, lo ko awọn eroja to lee sadede gbinna.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWasiu Ayinde: Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá

Ọkọ naa ni ajọ FRSC fikun pe o bajẹ loju ọna, to si n duro loore koore fun atunse ile epo ati rọba to n fa epo sinu ẹngini ọkọ naa, ti wọn n pe ni Fuel Pump, eyi ti wọn fi okun so pọ mọ ileepo, ti dẹrẹba ọkọ naa si lero pe yoo gbe wọn de Eko, amọ to gbinna loju ọna.

Awọn eroja to lee tete gbinna ti ọkọ naa si ko lo tete mu ki ina ọhun ran, to si ran eeyan mẹsan lọ sọrun ọsan gangan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTítí d'òní, Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé - Grandma Biafra

Oludari ajọ ẹsọ oju popo,ẹka tipinlẹ Ogun, Clement Oladele wa kẹdun pẹlu awọn to lugbadi ijamba naa, to si tun n rọ awọn awakọ lati maa tẹle ofin irinna tijọba gbe kalẹ, lati dena ewu.

"Ẹ ṣọ́ra fún ọkọ̀ sọọ́lẹ̀! Ọkọ̀ Sienna àdáni ni mo wọ̀, wọ́n fi ATM mi gba ₦400,000 jáde"

Image copyright @roshawn6869

Asa ki awọn eeyan maa duro si ẹgbẹ titi lati wa ọkọ ti wọn yoo wọ ti wa tipẹ tipẹ, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ewu lo so mọ asa yii.

Lọwọlọwọ bayii, awọn eeyan kan nilu Eko lo ti n figbe bọnu, ti wọn si n ka boroboro nipa ohun ti oju wọn ri nidi diduro si ẹgbẹ titi lati wọ ọkọ ero aladani, taa mọ si sọọlẹ.

Ni oju opo Twitter, obinrin kan lo n fi itara sọ ohun ti oju rẹ aburo ri nidi wiwọ ọkọ sọọlẹ nilu Eko, eyi to yẹ ko jẹ arikọgbọn fun gbogbo wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obinrin naa, Omotunde @Funkemyfun salaye pe aburo oun obinrin lo pe oun lojiji ni kete ta se ọdun tuntun 2020 tan, to si n sọkun kikankikan, eyi to mu ki n lọ baa nile rẹ.

Image copyright @Atren_

Ọmọtunde ni ọkọ Sọọlẹ Sienna ni aburo oun wọ ni deede aago marun idaji ni adugbo Berger, eyi to n lọ si Victoria Island, oun si ni ero keji ti wọn yoo gbe.

Gẹgẹ bi aburo rẹ ti salaye, "Ni kete ti mo joko ni awọn ọkunrin mẹrin wọle ti mi bii ero, ti wọn si n da ẹsẹ ati ipa bo mi kikankikan fun wakati kan. Wọn gbe mi lọ si agbegbe Ikeja, wọn se orisirisi pẹlu mi, bẹẹ ni wọn gbe omi oloro asidi sita pe awọn yoo daa si mi lara."

"Bi o tilẹ jẹ pe ori yọ mi pe wọn ko da asidi naa si mi lara, wọn ja mi si agbegbe Opebi lori ere, ti mo si fi ara gbọgbẹ."

O tẹsiwaju pe "Igbati-igbarun ni wọn fi n tẹle gbogbo ibeere ti wọn n bi mi, koda, wọn tun gba ẹrọ ibaraẹnisọrọ mi, ti wọn si n ka gbogbo ohun to wa nibẹ, wọn gba nọmba ATM mi, ti wọn si ni ki n maa tẹ owo ransẹ si apo asunwọn awọn ni kiakia ."

O salaye pe lẹyin o rẹyin, owo to to ẹgbẹrun lọna irinwo naira, ₦400,000 ni wọn gba lọwọ oun, ti gbogbo ara oun si kun fun ọgbẹ lorisirisi.

Ẹlomiran to tun salaye ohun ti oju aburo tiẹ naa ri, Roshawn @ roshawn6869 ni nigba to ku diẹ ka se ọdun Keresi lo wọ ọkọ ero adani de ibudokọ to gbe ọkọ rẹ pamọ si.

"Wọn gun mi lọbẹ ni gbogbo ara amọ a dupẹ pe ko ku, o wa laaye, amọ ko tii lee rin, ti ọgbẹ ori rẹ lọwọlọwọ bayii si buru jai."

Ọpọ eeyan miran tun sọ awọn ohun ti wọn koju nidi wiwọ sọọlẹ adani:

Ọpọ awọn eeyan to da si ọrọ yii lo wa gba awọn araalu nimọran lati sọra nidi wiwọ ọkọ sọọlẹ, paapa ọkọ Sienna, nitori ewu n bẹ loko Longẹ.