Wasiu Ayinde: Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá

Gbajugbaja olorin fuji, Wasiu Ayinde to ṣẹṣẹ jẹ oye mayegun Ilẹ Yoruba ti sọ fun BBC Yoruba pe, oye naa kii ṣe lati buga, ṣugbọn o jẹ lati tun ilẹ Yoruba ṣe.

Oluomo ṣalaye pe iṣẹ oun akọkọ gẹgẹ bii Mayegun ni lati ri pe alaafia jọba nilẹ Yoruba.

"Lati kekere ni mo ti n sapa lati ri pe Naijiria tẹsiwaju, bẹrẹ lati adugbo ti mo n gbe titi de ilẹ okeere, idi niyẹn ti mo ṣe n ba awọn oloṣelu ṣepọ, mo n bawọn sọrọ, wọn si n tẹti si imọran mi."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lori ọrọ ikọ Amotekun to ti di ariwo lẹyin ti ijọba apapọ ni ko ba ofin mu, o sọ pe ko sẹni to mọ ọmọ pọn bi ọlọmọ, fun idi naa, ko si eewọ ninu ka ṣọra ẹni, ṣugbọn ki ijọba fi oju ṣunukun wo ọrọ ọhun.