Blackout: Iléeṣẹ́ amúnáwá ní ìṣẹ́ ti ń lọ láti ṣe àtúnṣe ẹ̀rọ náà

Ẹrọ amunawa Image copyright @ayemojubar

Ẹrọ amunawa apapọ fun orilẹede Naijiria dẹnukọlẹ lọjọbọ oni, eyi to ko orilẹede Naijiria sinu okunkun biribiri fun igba akọkọ lọdun 2020.

Ileesẹ amunawa TCN fidi isẹlẹ naa mulẹ loju opo Twitter rẹ, eyi to wipe "ni deede aago kan ku isẹju mẹrindinlọgbọn lọsan oni ni aise deede ba ẹrọ amunawa to n pese ina ọba ni Naijiria, eyi to sọ awọn agbegbe kan si okunkun biribiri."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade ori ayelujara naa ni "amọ nigba to di ago kan kọja isẹju mẹwa ni ina ọba pada silu Abuja atawsn agbegbe mii to kan. A si n sisẹ lọwọ lori ẹrọ amunawa to dẹnu kọlẹ naa, ki ina ọba lee duro pada yika Naijiria."

Image copyright @ayemojubar

Bakan naa ni ileesẹ amunawa to wa ni agbegbe Ikeja nilu Eko sọ loju opo Twitter rẹ pe ẹrọ amunawa ni Naijiria bajẹ ni aago meji kọja isẹju mẹẹdogun lssan oni Ọjọbọ, lẹyin isẹlẹ akọkọ to waye.

"Ẹyin onibara wa, aayan ti n lọ lati se atunse ẹrọ naa, ẹ jọwọ, ẹ ba wa fara daa."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWasiu Ayinde: Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá

Bẹẹ ba gbagbe, o to igba mẹwa ti ẹrọ amunawa to n pese ina ọba yika orilẹede Naijiria bajẹ lọdun 2019.