Chioma Ikeaza-Uzodinma tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ búra wọlé fún ọkọ rẹ̀ ní Imo

Gomina Hope Uzodimma ati iyawo rẹ Image copyright OTHER

Chioma Ikeaza-Uzodinma ni iyawo gomina tuntun ti ipinlẹ Imo ti wọn ṣẹṣẹ bura wọle fun lọjọ kẹẹdogun oṣu kinni ọdun 2020 oun si ni o ti la gbogbo awọn to ku gẹgẹ bii iyawo gomina tọjọ ori rẹ kere ju.

Ẹni ọgbọn ọdun ni bẹẹ si ni agbẹjọro ni pẹlu. O un ni aya gomina Hope Uzodinma to ti kọkọ jẹ sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Iwọ Oorun ipinlẹ Imo ni agbegbe Orlu lọdun 2015.

Arabinrin Chioma Uzodinma ni yoo bẹrẹ si ni maa gba kiki ọlọla julọ aya gomina ipinlẹ Imo. Abiyamọ ni nile gomina pẹlu ọmọ mẹta, lara wn ni ibeji lanti lanti wa.

Iroyin taa gbọ ni wipe akinkaju arẹwa ọdọbinrin yii kawe gba oye ninu imọ ofin (LLB) ni fasiti ipinlẹ Imo nibi to ti kẹkọọ jade.

Bakan naa o di agbẹjọro ti wọn bura wọle fun lẹyin to tun kawe siwaju sii nile iwe giga ara ọtọ ti imọ ofin to wa ni ilu Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTítí d'òní, Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé - Grandma Biafra

Agbẹjọro ẹni ọgbọn ọdun yii ti ṣiṣẹ gẹgẹ akọsẹ amofin kaakiri awọn ile iṣẹ ni Emeka & Co law office, o ti ṣiṣẹ ni Rickey Tarfa & CO ati ni Chris Uche & Co law office.

Ilu Aba ni ipinlẹ Abia lo ti lo ọpọ igbesi aye rẹ lasiko naa o n jẹ orukọ baba rẹ Ikeaka ko to wa f Hope Uzodinma.

Oun nikan ni ọmọbinrin ti baba rẹ bi pẹlu ọmọ ọkunrin meji.

O jẹ ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ideato ni ipinlẹ Imo.