Biafra at 50: Umar ní àwọn tó ń bèèrè fún ogun kò mọ bí ogun ṣe rí ni

Ibrahim Umar

Ogun o ri bi iyan, ko si ri bi ẹkọ. Bi ayajọ aadọta ọdun ti ogun abẹle ti ọpọ mọ si ogun Biafra ṣe n lọ lọwọ, ọkan lara awọn soja nigba naa sọ iriri rẹ fun BBC.

Ọgbẹni Ibrahim Umar, ajagunfẹyinti ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin sọ fun BBC pe, ọta ibọn ti wọn yin mọ oun loju ogun ṣi tun wa lara oun di oni.

''Ọdun 1968 ni ọta ibọn ba mi ni ọrun nibi ti mo ti n gbe akẹgbẹ mi ti wọn yinbọn fun, ṣadeedee ni mo kan gbọ pau, ọrun mi ni ibọn naa ba,'' Umar lo woye bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkan lara wa yinbọn pada nibẹ ni gbogbo rẹ ti daru, si wọn si gbe mi digbadigba kuro nibẹ.

Umar ni oun wa nile iwosan fun ọpọ oṣu nibi ti oun ti gba itọju, ṣugbọn awọn dokita sọ fun oun pe ọta naa wa lori iṣan ọrun oun.

"Awọn dokita sọ fun mi pe tawọn le yọ ọta ibọn naa lara mi, mo le rọ lapa rọ lẹsẹ, idi ti ọta naa fi wa lara mi di oni niyẹn''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWasiu Ayinde: Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá

Nigba ogun Biafra yii naa ni Umar padanu ọrẹ rẹ Tanko Musa lẹyin tawọn omogun alatako dena de wọn.

Umar ni ọpọ ninu awọn ọrẹ oun lo ba ogun lọ, ṣugbọn o ni eyi to dun oun ju ni iku Musa.

Ajagunfẹyinti Umar wa gbadura pe ki orilẹede Naijiria ati ilẹ Afirika lapapọ ma ṣe ri ogun mọ.

Umar ni awọn to n pariwo ogun kaakiri ko mọ ohun ti wọn n pe ni ogun. O ni ninu igbo tawọn ti n jagun loun ti mọ oniruuru eso jẹ nitori ko si ounjẹ gidi kan fawọn lati jẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, Anthony Uko jẹ ọkan lara awọn soja to ja ogun Biafra lati ọdun 1969 ti ogun naa pari, ṣalaye pe nnkan ko rọgbọ f'oun lẹyin ogun Biafra, o ni oun n gbiyanju lati ṣe owo gẹgẹ bi afikun si owo ifẹyinti ti ijọba n fawọn.

Uko to jẹ ẹni ọdun mejidinlaadọrin sọ pe, ẹgbẹrun un lọna ogun naira lowo ifẹyinti awọn loṣu.

O wa rọ ijọba lati ṣe alekun owo naa nitori owo naa ko too na pẹlu bi gbogbo nnkan ti gbowo lori ni Naijiria lode oni.