Sotitobire: Ọlọ́pàá ní ₦800,000 ní àfurasí náà ń bèèrè láti fi ọmọ tí wọn ń wá sílẹ̀

Ijọ Sotitobire Image copyright Sotitobire

Egbirin ọtẹ, ba ti n pa ọkan ni omiran n ru ni ọrọ ọmọdekunrin Gold Kọlawọle, ọmọ ọdun kan ti wọn ji gbe nilu Akurẹ ninu ile ijọsin Sotitobire.

Idi ni pe laarọ oni yii ni ọwọ ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Ondo tẹ ọkunrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Elike Chibuzor, to ni oun loun ji Gold Kọlawọle gbe lọ.

Nigba to n fi idi isẹlẹ yii mulẹ fun BBC Yoruba, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ondo, Femi Joseph salaye pe, Chibuzor lo pe ileesẹ ọlọpa naa laarọ ọjọ Ẹti pe ọdọ oun ni Gold wa, ti wọn ba si fẹ gbaa pada, ki wọn san ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin naira (₦800,000) fun oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Afurasi naa, to ni ilu Akure ni oun ti n pe awọn ọlọpa ọhun, lo tun fi ye wọn pe, awọn eeyan kan lo ni ki oun parọ mọ Alfa Babatunde, ti ojisẹ Ọlọrun naa ko si mọ ohunkohun nipa bi ọmọde naa se sọnu ninu ile ijọsin Sotitobire.

Image copyright Gold Kolawole

Joseph ni, ni kete ti ọkunrin naa pe awọn lori aago, to si tun fi atẹjisẹ ransẹ lori owo to n beere yii, ni awọn bẹrẹ isẹ, to si foju han pe ilu Portharcourt lo ti n ba ileesẹ ọlọpa sọrọ, kii se ilu Akurẹ, gẹgẹ bo se sọ ninu ọrọ rẹ.

Image copyright BBC Sport

"Eyi lo mu ka bẹrẹ iwadi wa, ta si gbe ọkunrin naa, Chibuzor nilu Portharcourt to wa, amọ nigba to bọ si gbaga wa, lo yi ohun pada pe ọgbọn atijẹ ni oun n da, oun ko mọ ẹnikẹni tabi ohunkohun nipa isẹlẹ naa."

"Chibuzor fikun pe oun fẹ lu jibiti gba owo lọwọ ọlọpa ni, ọmọde ti wọn n wa naa ko si lọdọ oun, bẹẹ ni ẹnikẹni ko ran oun nisẹ lati parọ mọ pasitọ Babatunde."

Image copyright facebook

Joseph salaye pe, iwadi ileesẹ ọlọpa fihan pe ọkunrin Chibusor naa ti lọ sẹwọn ri nitori iwa lilu jibiti, eyi kii si se igba akọkọ rẹ ti yoo ko si gbaga ofin.

O wa fọwọ gbaya pe ọjọ Aje to n bọ ni wọn yoo fi oju Chibuzor Elike ba ile ẹjọ lori ẹsun lilu jibiti.

Bẹẹ ba gbagbe, ni aarọ oni ọjọ Ẹti oni ni alufa Babatunde, tii se pasitọ ijọ Sotitobirẹ to wa nilu Akure, nibi ti ọmọdekunrin naa ti sọnu, yọju sile ẹjọ, ti adajọ si ni ki wọn da pada sọgba ẹwọn nitẹsiwaju ẹjọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀ lẹ́yìn àṣeyọrí ìṣẹ́ abẹ dókìtà 70

Fídíò bí ìgbẹ́jọ́ Pásítọ̀ ìjọ Sotitobire ṣe lọ níléẹjọ́ Májísíréètì lónìí rèé

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFídíò bí ìgbẹ́jọ́ Pásítọ̀ ìjọ Sotitobire ṣe lọ níléẹjọ́ Májísíréètì lónìí rèé

Ile ẹjọ majisireeti to wa ni Oke Eda ni ilu akure, ipinlẹ Ondo ti sun igbẹjọ Pasitọ Alfa Babatunde ti ijọ Sotitobire ilu Akure siwaju di ọjọ karun un oṣu keji ọdun 2020.

Idajọ naa ti kuro nile ẹjọ majisireeti lonii eyi ti yoo waye ninu oṣu keji yoo waye nile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo.

Eyi tum si wi pe Pasitọ Babatunde yoo tun lọ lo nkan bii ọsẹ mẹta lọgba ẹwọn ni agbegbe Olokuta.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Tipatikuku lawọn ọlọpaa kogberegbe ati oṣiṣẹ ileeṣẹ ẹlẹwọn fi tu awọn akọroyin ka lasiko ti wọn gbe Pasitọ Alfa Babatunde wa si ile ẹjọ majistereeti ladugbo Oke Eda nilu Akure.

Ninu fọnran fidio ti o tẹ BBC lọwọ lati ile ẹjọ naa,a ri ti Pasitọ Babatunde sọkalẹ ninu ọkọ akero pẹlu awọn afunrasi mẹfa miran.

Pasitọ Sotitobirẹ wọ aṣọ olomi ewe ti wọn si ti ge irun rẹ.

Bi eeyan ko ba wo daada, o f le ma damọ pe oun lo bọ lẹ ninu ọkọ naa.

Ṣe ni ileẹjọ ti igbẹjọ Pasito Alfa Babatunde ti ile Ijọsin Sotitobirẹ yoo ti waye ti kun fọfọ pẹlu awọn to n reti Pasitọ naa.

Ninu awọn to ti wa ni ikalẹ ni awọn ọmọ ijọ rẹ, awọn mọlẹbi obi ti ọmọ wọn sọnu ati awọn akọroyin.

Akọroyin wa to n jabọ lati ibẹ fi awọn aworan ranṣẹ si wa ti o si ni laipẹ yii ni adajọ ati Pasitọ naa yoo kalẹ si ile ẹjọ.

Diẹ ninu aworan naa ree:

Lonii ọjọ Ẹti ni Alfa Babatunde to jẹ oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ Miracle Centre yoo foju ba ileẹjọ niluu Akure lori ẹsun to da lori bi ọmọ ọdun kan, Gold ṣe di awati ninu ṣọọṣi rẹ lọjọ kẹwaa oṣu kọkanla ọdun 2019.

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ lo gbe Alfa Babatunde lẹyin tawọn obi ọmọ naa fẹsun kan an pe o mọ nipa bi ọmọdekunrin naa ṣe di awati.

Loṣu kejila ọdun 2019 ni wọn kọkọ foju ba ileẹjọ Majisireti Oke Eda niluu Akure.

Adajọ paṣẹ pe ki wọn ju pasitọ naa si gbaga fun ọjọ mọkanlelogun, bakan naa ladajọ sọ pe igbẹjọ yoo tẹsiwaju lọjọ kẹtadinlogun oṣu kinni ọdun 2020.

Lonii naa ni adajọ yoo sọ bo ya ileẹjọ yoo gba oniduro Alfa Babatunde.

Alfa Babatunde atawọn ọmọ ijọ rẹ mẹfa ti wọn jẹ oṣiṣẹ nile ijọsin naa ni wọn jọ foju ba ileẹjọ lori ẹsun to da lori koko mẹta ti wọn fi kan wọn.

Àkọlé àwòrán Arabinrin Modupe Kolawole ni àwọn asọna to wa lẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ náà àti igbakeji oludari lo lọ sibl sùgbọ́n oludasilẹ o dasi ọ̀rọ̀ náà.

Ẹwẹ, ileẹjọ paṣẹ l'Ọjọru ọsẹ yii pe ki wọn si fi eeyan mẹrin ti wọn fẹsun kan pe wọn ṣekupa ọlọpaa nigba tawọn eeyan yabo ṣọọṣi naa ṣi atimọle.

Adajọ Charity Adeyanju paṣẹ pe ki wọn ṣi wa latimọle titi di ọjọ Aje ọsẹ to n bọ tii ṣe ogunjọ oṣu kinni ti igbẹjọ wọn yoo tẹsiwaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: