Grid Collapse: Ajọ TCN ní ìpèsè iná ọba ti padà ní ìlọ́po méjì lọ́jọ́ Ẹtì

ina Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ọpọ ero gba pe ko tọ si awọn EKEDC lati sọrọ lori ina bayii

Oju opo ikansiraẹ́ni lori ayelujara n gbona girigiri lẹyin ti ẹrọ amunawa apapọ orilẹede Naijiria dẹnukọlẹ l'Ọjọbọ, eyi to ko orilẹede Naijiria sinu okunkun biribiri fun igba akọkọ lọdun 2020.

L'Ọjọbọ ni ileesẹ amunawa TCN fidi isẹlẹ naa mulẹ loju opo Twitter rẹ pe, ni deede aago kan ku isẹju mẹrindinlọgbọn ọsan Ọjọbọ ni aiṣe deede ba ẹrọ amunawa to n pese ina ọba ni Naijiria, eyi to sọ awọn agbegbe kan si okunkun biribiri.

Bakan naa ni ileesẹ amunawa to wa ni agbegbe Ikeja nilu Eko sọ loju opo Twitter rẹ pe, ẹrọ amunawa ni Naijiria bajẹ ni aago meji kọja isẹju mẹẹdogun ọsan Ọjọbọ, lẹyin isẹlẹ akọkọ to waye.

Nibayii na, iroyin to n tẹ wa lọwọ ti sisọ loju rẹ pe ajọ̀ to n pese ina ọba nilẹ wa ti kede pe oun ti pese ina ọba pada sawọn agbegbe ti ko si ina ọba, ti ipese ina ọba si ti wa ni ilọpo meji.

Sugbọn ọrọ ina mọnamọna yii to n ṣe ṣegesẹge lawọn eeyan n gba, bi ẹni n gba igba ọtọ loju opo Twitter lati Ọjọbọ titi di oni ọjọ Ẹti.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aadota odun ree ti e ti n paro atunse ise yin fawon omo Naijiria lero awon kan

Ọpọ lori ayelujara ni wọn di ẹbi ina ọba to n ṣe ṣegesẹge naa ru minisita ile iṣẹ mọnamọna tẹlẹri, Babatunde Fashola.

Awọn eeyan yii ni Fashola ko ṣiṣẹ gidi lori ina ọba nigba to fi jẹ minisita.

Image copyright @ayemojubar

@viknaki sọ ni tiẹ pe ko si ohun tawọn ọmọ Naijiria ko tii ri lorilẹede ti ileeṣẹ amunawa (NEPA) ti n fi ọlọpaa mu ọfiisi ajọ NEPA mii nitori ko tete sanwo.

Ọgbẹni ChuksClassie tiẹ ni, ọrọ ileeṣẹ ina ọba n buru si ni, o ni nṣe ni wọn n jo ajorẹyin lojoojumọ, bi ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Manchester United.

Officialyugmiz sọ pe ileeṣẹ to n pese ina ọba gan an ko nina, o ni ohun ti wọn mọ naa ni lati maa pin biili fawọn onibara wọn.

Ajayi Muyiwa ṣalaye pe, ọjọ kan lawọn ni ina lagbegbe oun laarin ọjọ mẹta, oṣiṣẹ NEPA kan si tun laya ''lati sọ fun wa pe ki a maa yọ ọwọ ina ti wọn ba fun wa lo.''

@GallantMichael ni pe, to ba jẹ ina ọba ni ọkọ atọkẹlẹ n lo, ọpọ ọkọ ni ko ba ti dẹnukọlẹ nitori airina lo.

Bẹẹ ẹ o ba gbagbe, o to igba mẹwa ti ẹrọ amunawa to n pese ina ọba yika orilẹede Naijiria bajẹ lọdun 2019.