Collapse Building: Àjọ LASEMA ti gbe ọkùnrin náà lọ sílé ìwòsàn

Ọkunrin to ha si abẹ awoku ile ti ori ko yọ Image copyright LASEMA

Ọkunrin kan to ha si abẹ awoku ile to dawo laarọ ọjọ Ẹti ni ori ti ko yọ lọwọ iku ojiji.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni ọkunrin naa wa bayii, amọ ajọ LASEMa ti gbe digba-digba lọ sile iwosan fun itọju oju ẹsẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Se ni wọn fi ẹrọ ti eeyan fi n mi, to ni afẹfẹ ninu si imu ọkunrin naa, ki eemi rẹ lee jake, ni kete ti wọn fa yọ tan.

Image copyright LASEMA

Ko si si ẹni to lee sọ ibi ti ọkunrin naa ti sese, ti eruku ile to wo naa si wa lara rẹ.

Ilé alájà mẹ́ta tí wọn ń kọ́ lọ́wọ́ dàwó l'Eko, èèyàn kan há sínú rẹ̀

Image copyright LASEMA

Ile alaja mẹta ti wọn n kọ lọwọ lopopona Alasepe, ladugbo Agọ Ọkọta nilu Eko ti da wo lulẹ.

Atẹjade kan ti oludari agba fun ajọ Lasema nipinlẹ Eko, Oluwafẹmi Oke-Osanyintolu to fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba salaye pe ọkunrin kan lo ha sabẹ awoku ile naa.

Ọsanyintolu ni isẹ idoola ẹmi ti n lọ lọwọ lati fa ọkunrin naa yọ, ti isẹlẹ naa si ti se akoba fun awsn ile to yii ile awoku naa ka.

Image copyright LASEMA

Lasema ni ni kete ti wọn ba ti doola ẹmi ẹni to ha sinu ile naa ni awọn yoo wo awoku ile naa kanlẹ, ko maa baa jẹ ewu fun awọn ara adugbo naa.

Ọsanyintolu ni "Ni kete ta de sibi isẹlẹ naa, a woye pe ọkunrin kan ti ha sabẹ ile awoku naa, taa si ti bẹrẹ isẹ idoola ẹmi rẹ. Ni kete lẹyin eyi, si la wo ile naa kanlẹ."

Image copyright LASEMA