Amotekun: Àwọn ọmọ Nàìjíríà fi iṣẹ́ rán àwọn gómìnà sí Buhari

Aarẹ Buhari ati ami idanimọ Amotekun Image copyright @others

Ọpọ awọn ọmọ Kaarọ oojire ti n fi ohun ransẹ si awọn gomina to wa lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria lori bi ijọba apapọ se kede pe ikọ alaabo naa ko bofin mu.

Awọn ọmọ Yoruba naa ti wọn n fẹ ki awọn gomina wọn fi isẹ wọn jẹ fun aarẹ Muhammadu Buhari lasiko ipade ti yoo waye laarin aarẹ ati awọn gomina naa laipẹ yii.

Awọn gomina naa la gbọ pe wọn n gbero lati kan si aarẹ nilu Abuja, ki wọn si jọ se ipade pọ lati mọ ero rẹ lori ikede ti agbẹjọro agba fun ilẹ wa, Abubakar Malami se pe ikọ alaabo Amotekun ko ba ofin mu.

Nigba to n fi ero rẹ ransẹ si gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, Bukky Aweniade Akinbo wa n beere pe "Ki lo n dẹru ba ijọba apapọ gan lori ọrọ amọtẹkun, ti ọpọ eeyan si n kin lẹyin lori ibeere naa.

Adio Daud Ajidawura naa da si ọrọ ọhun nigba to ni oun fẹ ki wọn sọ fun aarẹ pe awọn gomina ilẹ Yoruba ko da ikọ Amotekun sile lati ṣe atako ẹnikẹni.

O tẹsiwaju pe "Nigba ti awọn ajinigbe atawọn Fulani darandaran n pa awon agbẹ ninu oko wọn, nibo ni aarẹ wa. Ilẹ Yoruba ni ẹto lati daabo bo ara wọn pẹlu eyikeyi ọna ti wọn ba mọ."

Musiliu Alabi Akoriola ni tirẹ sọ pe mi o le wa ku kankan ko lee joye ile baba rẹ, nitori naa, ki ẹya Yoruba ma gba ki awọn kan fi ẹtọ ati daabo bo ara wọn dunwọn.

Ni ti Dotun Bolu, ṣe lo fariga pe, ki wọn kuku pin orilẹ-ede Naijiria, ko si pada si boṣe wa tẹlẹ laye awọn baba Awolowo.

Ẹ wo awọn ohun miran ti awọn eeyan n sọ lori ọrọ ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀ lẹ́yìn àṣeyọrí ìṣẹ́ abẹ dókìtà 70