Sex for grade: Òkìkí olùkọ́ fásitì OAU míràn tún ti kàn lóríi pé ó fẹ́ bá akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lò pọ̀ fún máàkì

OAU Image copyright @OAUniversity
Àkọlé àwòrán Òkìkí olùkọ́ fásitì OAU míràn tún ti kàn lóríi pé ó fẹ́ bá akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lò pọ̀ fún máàkì

Ariwo kinla! Lo gbaye kan lori ikanni ayelujara bayii lori iroyin olukọ miran ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ ile ifẹ, OAU ti wọn ni aje tun ṣi mọ lori bayii o lori pe oun naa tun fẹ ba akẹkọọ lajọṣepọ ko to lee fun un ni maaki.

Arakunrin Bisi Babalẹyẹ ni ariwo rẹ gbode pe oun pẹlu fẹ jẹran sunkunsi akẹkọọ abẹ rẹ ni ẹka ẹkọ imọ ọrọ ilẹ Okeere, International Relations lọgba fasiti naa.

Iroyin sọ pe akẹkọọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Motunrayọ lo tu aṣiri sita lori ohun to n lọ laarin oun ati olukọ fasiti naa.

Koda akọsilẹ ibanisọrọ lori oju opo Whatsapp ati akasilẹ ohun ajọsọ ọrọ awọn mejeeji lori ẹrọ ibanisọrọ wa lara awọn ẹri maajẹmi niṣo ti wọn ni akẹkọọ naa fi sita.

Lati igba ti iroyin yii si ti jade ni awọn eeyan ti n pariwo ki awọn alaṣẹ fasiti OAU o gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ.

Bi a ko ba ni gbagbe, ni ọdun meji sẹyin ni irufẹ iroyin bayii ṣẹlẹ eyi ti aje rẹ ṣi mọ agba olukọ kan ni fasiti naa, iyẹn ni ẹka imọ iṣiro owo lori.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Akitiyan lati kan si alukoro ileewe giga naa lati mọ iha awọn alaṣẹ ileewe naa lo ṣi ja si pabo.

Diẹ lara awọn ẹri ti wọn n fi kaakiri ori ayelujara niyi:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Related Topics