Ààfá mẹ́ta réwọ̀n hé nípa ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ òjijì fún obìnrin kan pẹ́lù 36 mílíọ̀nù náìrà

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Wọn ti gbe Aafa Sule Shauibu, Wasiu Salami àti Francis Akinola lọ si ilé ẹjọ fún ẹ̀sùn pe wọ́n gbá Olayinka

Awọn ọlọpaa Ibadan nipinlẹ Ọyọ ni guusu Naijiria ti foju awọn aafa ti wọn fẹsun gbajuẹ kan hande ni Iyaganku.

Aafa Sule Shauibu to jẹ ẹni ọdun aadọrin ọdun ni wọn ni o jẹ olori awọn mẹtẹẹta naa.

Awọn amugbalegbẹ rẹ ti wọn fẹsun kan pe wọn jọ gba arabinrin Olayinka ni Aafa Wasiu Salami ẹni ọdun marundinlọgọta ati Francis Akinọla to jẹ ẹni ọdun marundinlaadọta.

Ẹsun jibiti mẹta ni wọn fi gbe wọn wa sile ẹjọ majisreeti ni Iyaganku ni iluj Ibadan

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn

Sajẹnti Olalekan Adegbitẹ to ṣaaju ikọ agbofinro to gbe awọn ti a fẹsun kan wa sile ẹjọ ṣalaye pe awọn mẹtẹẹta gba owo lọwọ arabinrin Olayinka Ishioye lọna aitọ.

O ni wọn gba miliọnu mẹrindinlogoji lọwọ rẹ lọdun 2015 pelu ileri lati baa wa ojutu si ogun aye rẹ ti o nii lara lasiko naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionO leè má mọ̀ bóyá o ní àrùn HIV/AIDS o! Wo àwárí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ yìí

Wọn ni wọn fẹ fi owo naa seto adura ati awọn aajo miran lati yọ arabinrin Olayinka kuro ninu iṣoro ara níni to de baa lọdun 2015 ni.

Obinrin naa ni wọn ni wọn fẹ pese iranlọwọ ninu ẹ̀mí fun oun ni nigba naa.

Adegbitẹ ni eyi si ṣe lodi siu iwe ofin ati iwa ọdaran ni Naijiria abala 383 ni eyi to tọ si ijiya ni abala 390 (9) ati abala 415 ati ti 516 iwe ofin iwa ọdaran Cap 38; Vol II ti ọdun 2000 ni ipinlẹ Oyo.

Agbẹjọro Hammed N. A ati Adesanya D. S ti wọn n ṣoju awọn olujẹjọ beere fun gbigba oniduro awọn Aafa mẹtẹẹta lẹyin ti wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun naa.

Wọn ni kii ṣe pe awọn ṣe gbajuẹ fun Arabinrin Olayinka nigba to gbe iṣoro wa si ọdọ wọn gẹgẹ bii Aafa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIllegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ

Adajọ Adesina S. A pada gba oniduro awọn mẹtẹẹta ti wọn fẹsun jibiti ninu iṣẹ Ọlorun kan naa pẹlu miliọnu mẹrin naira ari awọn oniduro agba meji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀ lẹ́yìn àṣeyọrí ìṣẹ́ abẹ dókìtà 70

Adesina sun igbẹjọ naa di ọjọ kẹta. oṣu keji ọdun 2020.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTítí d'òní, Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé - Grandma Biafra