Ẹ má mu gaarí mọ́ nítorí ìbà Lassa- Dókítà Boniface

Image copyright @Others
Àkọlé àwòrán Dokita Okolo ni ọpọ ninu awọn eku to maa n ko arun iba Lassa lo n rin ninu gaari ti awọn eeyan n mu

Adari ẹka eto ilera ni ipinlẹ Enugu, Oniṣegun oyinbo Boniface Okolo ti kilọ fawọn eniyan Naijria.

O ni iwadii ti fihan pe lara gaari ni awọn ekute ile ti maa n tan arun iba Lassa kalẹ.

Okolo fi ikilọ yii sita lasiko to n ni ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin Naijiria (NAN) nilu Enugu.

O ni o ti di dandan ki eleto ilera kilọ fawọn ara ilu lori ipa ti ekute ile ati gaari n ko ninu itankale Iba Lassa.

Dokita Okolo ni o ṣe pataki lati kilọ nipa mimu gari lasiko yii nitori pe wọn kii fi omi gbigbona muu bi ẹba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Owó tí mo ń rí lórí Garri ni mo fi ń ran ọkọ lọ́wọ́'

Dokita Boniface ni omi gbigbona ti wọn n fi si ẹba fi tẹẹ a maa pa kokoro arun lassa ninu gaari ṣugbọn omi tutu ko ni pa kokoro naa ti awọn eeyan ba fi mu gari.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEku ọlọmu pupọ lo nfa iba Lassa

Dokita ni o san lati fi gari tẹ ẹba ju lati muu lọ nitori itankalẹ arun iba lassa yii.

O ni awọn oṣiṣe eleto ilera n gbiyanju lati gbogun ti itankalẹ arun buruku yii paapaa nipinlẹ Enugu ṣugbọn gbogbo ara ilu gbọdọ fọwọsowọpọ lati ja ija ilera naa yanju ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn

Bakan naa lo tun kilọ pe ki awọn eeyan ma fọ eso ati ewebẹ wọn daadaa ki wọn to jẹẹ.

Ni ipari o ni ki onikaluku ṣọra lori ọna ti wọn n gab fi ounjẹ pamọ ki ekute ile ma ti lọ tẹnu bọọ ki wọn si ko arun Lassa sinu ounjẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTítí d'òní, Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé - Grandma Biafra

O ni ki awọn eeyan maa lo ike ọlọmọri to de daadaa ki wọn to fi ounjẹ silẹ ninu ikoko lai dee daadaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀ lẹ́yìn àṣeyọrí ìṣẹ́ abẹ dókìtà 70