PDP yóò wọ́de lọ́jọ́ Ajé nítorí ìdájọ́ ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Imo

Awọn oluwọde ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP Image copyright @OfficialPDPNig

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni lọjọ Aje, ogunjs oṣu kinni ọdun 2020 lawọn yoo fọn sigboro lati fi ẹhonu han lori idajọ ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria eleyi to yi Emeka Ihedioha lagbo da sina gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Imo.

Nilu Abuja ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe iwọde naa yoo ti waye.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP gbe sita, awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa bẹrẹ lati ori alaga rẹ, Uche Secondus ti fọwọsi iwọde naa pe ko waye.

Oniruuru awijare ati ariyanjiyan lo ti waye lori idajọ naa to waye lọjọ iṣẹgun eyi to sọ Hope Uzodinma ti ẹgbẹ oṣelu APC di gomina ipinlẹ Imo lẹyin ti ile ẹjọ to gaju lorilẹede Naijiria yẹ aga mọ Ihediora nidi.

Image copyright @OfficialPDPNig

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni iwọde naa yoo lọ nirọwọ rọsẹ ko si ni ni rogbodiyan kankan ninu rara.

Nibayii awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti bẹrẹ iwọde lawọn ipinlẹ kọọkan ni ọjọ Aiku ni imura silẹ fun eyi ti yoo waye nilu Abuja lọjọ Aje.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn