Abule Egba Explosion: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò níbi ọ̀pá epo tó gbiná

Agbegbe Abule Egba Image copyright @adebolaolu2019

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati agbegbe Abule Egba, ipinlẹ Eko ti ọpa epo bẹntiroo ti gbina ni wi pe eeyan marun un lo ba iṣẹlẹ naa rin.

Ninu eeyan marun un ọhun, ọmọdebinrin to jẹ ọmọ ọdun marun un kan wa nibẹ, agbalagba ọkunrin mẹta ati agbalagba obinrin kan.

Bakan naa bii eeyan ogun lo fara pa ṣugbọn ti wọn tọju wọn loju ẹsẹ nibi iṣẹlẹ naa.

Ile bii mẹfa, ile itaja mẹtadinlogun ati ọkọakoyanrin mẹtalelọgbọn, ọkọ ayọkẹlẹ mẹta ati kẹkẹ NAPEP alupupu mẹta.

Image copyright Getty Images

Lasiko ti ọ̀pá epo bẹ́ntiró naa gbiná l'Eko, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lo lọ síi.

Oluwatoyin Ojo to jẹ ọkan lara awón alafojuri to wa nibi iṣẹlẹ naa ni ori lo ko oun yọ.

O ni ko pẹ ti oun n jade lọ si agbegbe Meiran ni alẹ ana ọjọ Aiku ti oun k'ẹfin ero to pọ ti wọn n gbọn epo bẹntiroo nitosi ile epo nla ti NNPC to wa ni opopona Ekoro.

Oluwatoyin Taiwo Ojo ṣalaye pe bi oun ṣe ri ero to pọ yii to tun ti fa sunkẹrẹ- fakẹrẹ ọkọ ni oun ba ṣeri pada.

Image copyright LASEMA

Oluwatoyin ni ko pe iṣẹju aaya lẹyin ti ọkọ oun pada ni oun gbọ ariwo nla ti ina ti sọ ti o si dabi ala ti ọpọ ero n sa asala fun ẹmi wọn.

Koko to gba ẹnu awọn eeyan ni owuro yii ni pe asiko ti to lati mọ pe gbigbon epo bentiroo to n danu kọ ni ọna abayọ lasiko yii nitori ewu rẹ pọ ju owo ti o maa ri nibẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHepatitis: A kò leè kóo nípa dídìmọ́ ara ẹni

Bayi, ajọ LASEMA to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ni wọn ti ri ina naa pa nitori pe wọn ti ti ọpa epo nla to n gbe epo naa bọ.

Alukoro ajọ naa, Nosa Okunbor ni igbesẹ ti awọn ajọ ọhun gbe ni kia tete jẹ ki wọn rii pa loru ana.

O ni wọn ti fidiẹ mulẹ pe agbalagba meji ati ọdọmọkunrin kan ti doloogbe bayii pẹlu ọkọ akẹru mọkanla yatọ si ile to kun fun ọpolọpọ dukia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTítí d'òní, Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé - Grandma Biafra

Kini o ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

Iná sọ, dúkìá parẹ́, níbi ọ̀pá epo tó gbíná l'Eko

Ọpa epo bẹntiro kan tun ti bu gbamu ti ina si sọ lagbegbe Oke odo ni ilu Eko.

Gẹgẹ awọn iroyin to n jade lati agbegbe naa ṣe sọ, ọpọlọpọ dukia ati ohun ini lo n jona lọwọ bayii nibẹ.

Iwadii fihan bayii pe awọn ọkundun ẹda ti n tori owo odi bẹ ọpa epo ijọba lagbegbe naa lati ji epo fa lo ṣokunfa ina ajoranju mọọ naa.

Ni asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, a ko ti fi idi rẹ mulẹ boya ẹmi lọ si iṣẹlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn

Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ wa...