premier league: Liverpool to ọrẹ́ sí ẹ̀yìn Manchester United pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo

Agblu Man United lu igi ile Liverpool

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Itakun Manchester United gbiyanju titi ṣugbọn ko lee da erin Liverpool duro lọna pe ko maa tẹsiwaju ninu ilepa rẹ lati gba liigi Gẹẹsi ti saa yii.

Ni ifẹsẹwọnsẹ to waye lalẹ ọjọ Aiku ni papa iṣire Anfield, ami ayo kan si odo ni Liverpool fi gbẹyẹ mọ Manchester united lọwọ.

Ni iṣẹju kẹrinla ifẹsẹwọnsẹ naa ni Virgil, agbabọọlu Liverpool gba goolu kan ṣoṣo to pin awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji niya wọle.

Bi o tilẹ jẹ wi pe Liverpool gba bọọlu si awọn manchester United ni igba meji miran lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa, wọn ko kaa nitori awọn aṣemaṣe ti wọn ṣe ṣaaju rẹ.

Amọṣa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelaadọrun ti orun n rebi atiwọ ni Mohammed Sallah ba tun fi ọba lee fun Liverpool.

Pẹlu abajade ifẹsẹwọnsẹ naa, Liverpool lo ṣi n lewaju atẹ igbelewọn liigi ilẹ gẹẹsi bayii pẹlu ami ayo mẹrinlelọgọta ninu ifẹsẹwọnsẹ mejilelogun nigba ti Manchester United ṣi di ipo karun un rẹ mu pẹlu ami ayo mẹrinlelọgbọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtalelogun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu ọrọ ti o sọ ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ ọhun, olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp jẹ ko di mimọ pe awọn agbabọọlu oun yoo da ọpọlọpọ wahala silẹ fun Manchester United nitori pe bi awọn agbabọọẹu oun ba gba bọọlu daradara, awọn agbabọọẹu Manchester united yoo maa sa kijokijo lati di oju ile wọn ni o.

Ni tirẹ, olukọni Manchester United, Olu Gunner Solkjaer ni awọn mọ pe aja to wọle ts ẹkun lọrọ awọn nitori ibi to le gidigodo lawọn wa yii, ikọ to si ja fafa lawọn wa koju.

Ni saa kini, Liverpool ta ayo gidigidi, ṣugbọn laifọta pe,