Supreme court judgement: Ta ni Gómìnà Bala Mohammed?

Bala Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ta ni Gómìnà Bala Mohammed?

Wọn bi Bala Abdulkadir Mohammed lọjọ karun un, oṣu Kẹwaa, ọdun 1958 nipinlẹ Bauchi.

O kẹkọọ gboye imọ ijinlẹ ninu ede Gẹẹsi ni Fasiti ilu Maiduguri lọdun 1982.

O ṣiṣẹ akọroyin pẹlu iwe iroyin The Democrat, ko to di oṣiṣẹ ijọba laarin ọdun 1984 si 2000.

O fẹyinti gẹgẹ bi Oludari ẹka amojuto ni ajọ to n wo òye oju ọjọ ni Naijiria.

Lẹyin naa lo di oluranlọwọ pataki fun gomina ipinlẹ Bauchi nigba naa, Isa Yuguda, laarin ọdun 2000 si 2005.

Wọn dibo yan an sipo sẹnetọ ẹkun idibo Guusu Bauchi l'ọdun 2007.

Aarẹ nigba kan fun Naijiria, Goodluck Jonathan yan an ni Minisita olu ilu Naijiria, FCT, lọdun 2010.

O wọle sipo gomina ipinlẹ Bauchi labẹ ẹgbẹ PDP, lẹyin ti atundi ibo waye ninu idibo apapọ ọdun 2019.

Ta ni Waziri Tambuwal?

Ọjọ Kẹwaa, oṣu Kinni, ọdun 1966 ni wọn bi Tambuwal, nipinlẹ Sokoto

O pari ileewe alakọbẹrẹ l'ọdun 1979, o si darapọ mọ ileewe olukọni, Dogan-Daji Teachers College nibi to ti gba iwe ẹri Teachers Grade 11 l'ọdun 1984.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFarms to You: Irú ajílẹ̀ wo ló yẹ fún lílò lásìkò yìí- Aisha

Lẹyin naa lo darapọ mọ Fasiti Usman Dan Fodio nilu Sokoto, nibi to ti kẹkọọ gboye imọ ofin l'ọdun 1991.

Tambuwal bẹrẹ si ni kọ nipa oṣelu ṣiṣe laarin ọdun 1999 si 2000, nigba to n ṣe amugbalẹgbẹ lori ọrọ ile aṣofin, fun Sẹnetọ Abdullahi Wali, to jẹ olori ile aṣofin agba lasiko naa.

Tambuwal Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ta ni Gómìnà Aminu Waziri Tambuwal?

Wọn dibo yan an si ipo aṣoju ẹkun Kebbe / Tambuwal Federal Constituency nipinlẹ Sokoto l'ọdun 2003 labẹ ẹgbẹ oṣelu ANPP.

Tambuwal di awọn ipo kan mu nile aṣofin. bíi lọdun 2005, o di Olori ọmọ ẹgbẹ to kere ju nile aṣofin, ko to o di pe o lọ darapọ mọ ẹgbl PDP.

O tun di Akojanu ile lẹyin to tun pada wọle ibo lọdun 2007.

Bakan naa lo jẹ ọmọ igbimọ oriṣiriṣi nile aṣofin ko too di Tambuwal di Olori ile aṣoju-sofin kẹwaa

Ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2011, Aminu Tambuwal di Olori ile aṣoju-ṣofin pẹlu ilana to mu iriwisi dani.

Oun lo gba ipo lọwọ Olori ile tẹlẹ, Dimeji Bankole.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn

Lọdun 2015, Aminu Tambuwal dije dupo gomina ipinlẹ Sokoto, o si wọle labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

L'ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2018, Tambuwal fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ, o si pada si PDP.

Lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP lo si ti dupo gomina l'ọdun 2019, to tun fi wọle saa keji.

Abdullahi Ganduje Image copyright Twitter/Abdullahi Ganduje
Àkọlé àwòrán Ta ni Gómìnà Kano Abdullahi Umar Ganduje?

Ta ni Gomina Abdullahi Ganduje?

Ọjọ Aje lawọn adajọ ẹlẹni meje nile ẹjọ giga julọ niluu Abuja sọ pe ki Gomina Abdullahi Umar Ganduje maa ba iṣẹ rẹ lọ gẹgẹ ni Gomina ipinlẹ Kano.

Ile ẹjọ da ẹjọ ti Abba Yusuf to jẹ oludije fẹgbẹ oṣelu PDP nu ninu eyi to ti sọ pe eeru wa ninu ibo to gbe Ganduje ti ẹgbẹ oṣelu APC wọle.

Amọ awọn adajọ meje nile ẹjọ to ga julọ dajọ pe awọn agbẹjọro PDP kuna lati fidi rẹ mulẹ pe eeru wa ninu ibo to gbe Ganduje wọle.

Pẹlu iadajọ yii, Gomina Ganduje yoo wa lọfiisi gomina ipinlẹ Kano titi di ọdun 2019.

Igbe aye Ganduje ree:

A bi Abdullahi Umar Ganduje lọdun 1949 labule Ganduje ni ijọba ibilẹ Dawakin Tofa nipinlẹ Kano.

O bẹrẹ si ni kọ Kewu ni kekere labule rẹ ko to lọ si ile iwe alakọbẹrẹ Dawaki Tofa laarin ọdun 1956 si 1963.

Ganduje teṣiwaju ẹkọ rẹ nile iwe girama lọdun 1964 si 1968.

Image copyright Twitter/Abdullahi Ganduje

Ganduje kẹkọọ nile iwe olukọni bẹrẹ lati ọdun 1969 di ọdun 1972, lẹyin naa lo lọ si fasiti Ahmadu Bello niluu Zaria, ipinlẹ Kaduna nibi to ti kẹkọ gboye lọdun 1975.

Ganduje kẹkọọ gboye keji ni fasiti Ado Bayero lọdun 1979, bakan naa lo tun kẹkọọ gboye keji ninu isakoso ilu.

Bakan naa ni Ganduje tun kẹkọọ gboye ni fasiti ilu Ibadan lọdun 1993.

Ganduje wọ agbo oṣelu

Ganduje darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NPN nibi to to ṣe igbakeji akọwe lọdun 1979 si 1980.

O dije ninu eto idibo sile aṣoju-ṣofin niluu Kano lọdun 1979 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NPN, ṣugbọn o fidi rẹmi.

ọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 1998, o si jẹ igbakeji gomina laarin 1999 si 2003.

Image copyright Twitter/Abdullahi Ganduje

Ganduje dipo oludamọran fun minisita eto aabo, Rabiu Kwankwaso laarin ọdun 2003 si 2007.

O wọle ibo gomina ipinlẹ Kano lọdun 2015.

Ganduje tun wọle ibo gomina fun saa keji lọdun 2019, amọ ẹgbẹ oṣelu PDP pee lẹjọ pe eeru lo fi wọle.

Ṣugbọn ile ẹjọ giga julọ daa lare lọjọ Aje, ti wọn ko ba yọọ nipo, Ganduje ni yoo ṣe gomina ipinlẹ Kano di ọdun 2023.