Amotekun: Soyinka fèsì padà fún Balarabe Musa pé ó kùnà lóríí ikọ̀ aláàbò náà

Aworan Balarabe Musa ati Soyinka

Ọjọgbọn Wole Soyinka ti dasi ọrọ Amọtẹkun to n ja rain rain ni Naijiria eyi ti wọn ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Kaduna, Balarabe Musa sọ nipa ikọ alaabo Amotekun.

Ninu atẹjade kan to fisita, Soyinka sọ pe Balarabe kuna pẹlu ọrọ to sọ nipa Amọtẹkun, eyi to ni o lee se okunfa iyapa ni orilẹede Naijiria ati agbekalẹ orilẹede Oduduwa.

Soyinka ni oun to ma n da wahala silẹ ni ''ki awọn eeyan kan ma mu ọrọ ibẹru gẹgẹ bi ọrọ ododo tabi ki ijọba ati awọn ẹya kan ma gbe igbesẹ latari ibẹru to gba ọkan wọn''

O ni iru iwa bayi kii labọ nitorinaa o wu oun ki Balarabe yẹra fun iru ọrọ tabi iwa bayi.

Balarabe gẹgẹ bi ohun ti iwe iroyin kan sọ lo ni idasilẹ Amẹtẹkun jẹ ọna kan ti ẹya Yoruba fẹ gba lati mu ipinya Naijiria wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa rọ aarẹ Buhari lati maṣe faye gba idasilẹ ikọ alaabo Amọtẹkun tawọn Gomina ipinlẹ Kaarọ o jiire dasilẹ.

Yatọ si ọrọ ọjọgbọn Soyinka, pupọ awọn to jẹ olori ẹgbẹ, yala ti Yoruba ati awọn agbẹjọro to fi mọ awọn amofin, lo ti da si ọrọ yii.

Ọlọ́pàá dènà ìwọ́de fún àtìlẹyìn ikọ̀ Amotekun ní Eko

Image copyright Others

Iwọde fun itẹwọgba eto Amotekun to lọ gaaraga lawọn olu ilu ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba lọjọ Aje, lo pakasọ nilu Eko.

Idi ni pe ọrọ di boolọ, ko ya fun mi nigba ti awọn agbofinro ya bo ibudo ti wọn kede pe eto iwọde alaafia naa yoo ti gberesọ.

Iwọde naa, ti ẹgbẹ agbarijọpọ awọn ọmọ Yoruba, Yoruba World Congress (YWC) kede pe yoo gbera ni ibudo igbafẹ Gani Fawẹhinmi ladugbo Ọjọta nilu Eko ni awọn ọlọpaa ti pa.

Ni kutu hai owurọ ọjọ Isẹgun si lawọn osisẹ ọlọpaa ti ya bo ibudo naa, ti wọn si ti ẹnu ọna abawọle ibẹ, ki awọn eeyan to n gbero lati se iwọde maa baa ri aaye pejọ.

Koda, ọkọ ọlọpa to wa nikalẹ nibudo ọhun le ni ogun, tawọn agbofinro ti oju wọn ko rẹrin si duro wa wa wa, bi esinsin ba si ta firi nibẹ, wọn yoo wọn.

Ẹni tó bá ń bá Amotekun jà, ló fẹ́ bá Yorùbá jà - Yoruba World Congress

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAmotekun: Ikọ̀ aláàbò yíì kọjá ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, àwọn ọdẹ àti Àgbẹ̀kọ́yà ló pọ̀ nínú rẹ̀

Kaakiri awọn olu ilu ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba lawọn eeyan ti jade lọjọ Aje lati se iwọde alaafia fun itẹwọgba ikọ alaabo alajumọse lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, taa mọ si Amotekun.

Nibi iwọde naa, ti agbarijọpọ ẹgbẹ ọmọbibi ilẹ Yoruba, Yoruba World Congress, ni asaaju iwọde naa nilu Ibadan, Kunle Adesọkan ti kede pe ẹnikẹni to ko ba fẹ tẹwọgba eto Amotekun, ni ko fẹran ilẹ Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adesọkan tun fikun pe ẹni to ba n ba eto Amotekun ja, lo n ba iran Yoruba ja, to si kesi awọn gomina ilẹ Yoruba lati mase bẹru nitori digbi ni awọn wa lẹyin wọn.

Bakan naa nilu Akurẹ, awọn eeyan to se iwọde nibẹ kede pe ikọ alajumọse Amotekun kọja ọrọ ẹsin nitori awọn ọdẹ ati awọn Agbẹkọya lo wa nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFarms to You: Irú ajílẹ̀ wo ló yẹ fún lílò lásìkò yìí- Aisha

Wọn fikun pe ikọ alaabo Amotekun ko wa lati dojukọ ẹya Fulani abi ẹnikẹni, sugbọn gbogbo ẹni to ba n huwa ọdaran ni Amotekun yoo maa doju ija kọ, onitọun ko baa jẹ ẹya Yoruba.

Àwọn ọmọ Yorùbá bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de àláfíà fún ìtẹ́wọ́gbà ètò Amotekun

Agbarijọpọ ẹgbẹ ẹya Yoruba, Yoruba World Congress n bẹrẹ iwọde alaafia lati kede atilẹyin wọn fun ifilọlẹ eto aabo alajumṣe nilẹ Yoruba ti wọn pe ni "Operaton AMOTEKUN".

Eto Amotekun yii naa ni awọn gomina lẹkun iwọ oorun Naijiria pawọpọ gbe kalẹ lai naani ẹgbẹ oselu ti wọn wa se, ilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Ọyọ si ni eto ifilọlẹ naa ti waye.

Alaye awọn to ṣe agbatẹru iwọde naa nipa ohun to mu wọn gunle iwọde ọhun ni wi pe ko bojumu ki ijọba apapọ to n ṣe atilẹyin fun ikọ HISBAH ni ẹkun ariwa orilẹede yii, kede pe ifilọlẹ eto AMỌTEKUN nilẹ Yoruba ko ba ofin Naijiria mu.

Ọpọlọpọ àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọdọ ni wọn tú jáde ní witiwiti láti fi ìfẹ́ hàn sí idasile eto Amotekun tí ìjọba káàkiri ilé Yoruba gbé kalẹ.

Adari iwọde Amotekun nilu Akure, Tola Ogunlalaka ṣàlàyé pé, akoko ti tó kí ètò alajumọse naa bẹ̀rẹ̀ àti wí pé, ẹranko tí ó jẹ Amotekun leè ṣọdẹ dáadáa.

Awọn eeyan miran tí ó bá iko BBC Yoruba sọrọ, Ogbeni Jephrey Abidoye ṣàlàyé pé, àsìkò ti to láti mú eto ààbò ilé Yoruba gbòòrò sì.

Lọwọlọwọ bayii, iwọde naa n lọ lọwọ ni ilu Eko, Abeokuta, Ibadan, Osogbo, Akure ati Ado-Ekiti. Àwọn ọdọ àti àwọn ọdẹ náà kò gbeyin nínú iwode naa.