Aguda Ogba Fire: Iná míì tún sọ ní Ọgba, nílùú Eko!

OGBA
Àkọlé àwòrán Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà ṣe ojú rẹ̀ ní ó bẹrẹ ní déédé ago márun un ní Ọjọ́ Eti kí àwọn panapana to dé.

Awọn oṣiṣẹ panapana ti wa ni agbeegbe Aguda, Ogba ni ipinlẹ Eko nibi ti ina ti sọ ni irolẹ Ọjọ Eti.

Awọn ti ọrọ naa ṣe oju wọn ni wn n sun ina ni ilẹ kan ni agbeegbe naa, ki o to di wi pe ina naa wa bẹrẹ si ni ran.

Arabinrin Funmilayo Taiwo ti ina naa ran ile itaja rẹ sọ wi pe oun ati awọn ara agbeegbe lo ja ilekun ile naa lati lọ pa ina naa ki awọn panapana to de.

Ni bayii awọn panapana ti dawọ ina naa duro, ti ohun gbogbo si ti pada si ipo.

Ti a ko ba gbagbe, ọmọ ọdún márùn-ún àti àgbà mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pá epo bẹntiróò tó gbiná ní Abule Egba lọ láìpẹ́ yìí.

Sanwo-Olu pèsè ìpàgọ́ tó wà ní Igando fáwọn tí iná jólé wọn ní Abule Egba láti gbé

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti paṣẹ ipese eto iranwo fun awọn olugbe agbeegbe ijọba ibilẹ Agbado/Oke Odo nilu Eko, lẹyin ti wọn lugbadi ọpa epo bẹntiroolu to gbina.

Image copyright @adebolaolu2019
Àkọlé àwòrán Ọmọ ọdún márùn-ún àti àgbà mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pá epo bẹntiróò tó gbiná ní Abule Egba lọ láìpẹ́ yìí.

Ajọ eleto pajawiri ni ipinlẹ Eko, Lasema ni, gomina Sanwo-Olu gbe igbeṣẹ yii lẹyin ti awọn Alaga ijọba ibilẹ naa ke gbajare si fun ipese eto iranwọ.

Lasema ni awọn eniyan ti wọn nilo iranwọ ni agbeegbe naa to ọọdunrun eniyan, ti awọn obinrin ati ọmọde si wa ni ara wọn.

Wọn fikun pe Gomina Sanwo-Olu ti buwọ lu ki wọn fun awọn eniyan to lugbadi iṣẹlẹ naa ni ipagọ to wa ni Igando Relief Camp, Igando ni ipinlẹ Eko, ki wọn maa gbe fun igba diẹ na.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọ ọdún márùn-ún àti àgbà mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pá epo bẹntiróò tó gbiná ní Abule Egba lọ láìpẹ́ yìí.

Bakan naa ni wọn ṣeleri pe awọn yoo ma a fito awọn ara ilu leti bi o ba ṣe n lọ, lori eto iranwọ fun awọn eniyan agbeegbe naa.

Ọmọ ọdún márùn-ún àti àgbà mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pá epo bẹntiróò tó gbiná ní Abule Egba lọ láìpẹ́ yìí.

Bakan naa bii eeyan ogun lo fara pa ṣugbọn ti wọn tọju wọn loju ẹsẹ nibi iṣẹlẹ naa.

Ile bii mẹfa, ile itaja mẹtadinlogun ati ọkọ akoyanrin mẹtalelọgbọn, ọkọ ayọkẹlẹ mẹta ati kẹkẹ NAPEP alupupu mẹta naa ba iṣẹlẹ naa lọ.

Àwọn olùgbé Tarkwa Bay ń fọ́ ọ̀pá epo, jí epo ta, la ṣe lé wọn - Iléeṣẹ́ Ológun

Ileesẹ ologun oju omi ti salaye ohun to faa ti wọn fi n fi tipa-tikuuku le awọn olugbe Tarkwa Bay to wa ni erekusu Eko, eyi ti eeyan le gba oju omi nikan wọ ibẹ.

Image copyright @justempower
Àkọlé àwòrán Osu Kejila ọdun 2019, paapa lati ọjọ aisun ọdun Keresi ni awọn ologun ti ya bo agbegbe Tarkwa Bay, ti wọn si n le awọn eeyan tipa tikuuku.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, agbẹnusọ fun ikọ ologun oju omi to lewaju igbesẹ lile awọn eeyan agbegbe ọhun, Ọgagun Thomas Otuji salaye pe, awọn ọpa epo to n gbe epo wa silu Eko ati awọn etikun lo gba agbegbe ọhun kọja eyi ti wọn maa n fọ lojoojumọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Otuji ni "Afojusun wa ni lati daabo bo awọn irinsẹ to jẹ ti ajọ elepo rọbi nilẹ wa lọwọ awọn eeyan to n fọ ọpa epo kiri. Wọn ti kọ ile sori awọn ọpa epo naa, ti wọn si n fa epo ta lọna aitọ."

Image copyright @justempower

Amọ Otuji ko sai fikun pe bi o tilẹ jẹ pe kii se gbogbo awọn eeyan to n pe ni agbegbe naa lo n ji epo ta, sugbọn ẹni to gbe epo laja ko jale, bi ẹni to gbaa silẹ, nitori ti wọn ko ba tu asiri awọn eeyan to n ji epo fa lọna aitọ ni ayika wọ, gbogbo wọn ni wọn jọ jẹbi.

Nibayi naa, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lorisirisi lo ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ tawọn ologun naa gbe ati igbiyanju wọn lati le awọn olugbe erekusu Tarkwa Bay ni erekusu Eko.

Image copyright @justempower

Ẹgbẹ kan to pe ara rẹ ni Nigerian Slum/Informal Settlement Federation, ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Isẹgun oni, koro oju si igbesẹ ijọba lati le ẹgbẹrun mẹwa eeyan to n gbe ni erekusu ọhun pẹlu ipa.

Gẹgẹ bo se jẹyọ ni oju opo ikansiraaẹni ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni kan, @justempower, jei, ẹgbẹ naa ni ọna ipa ti ijọba apapọ n gba le ogunlọgọ ero kuro ninu ile wọn lai bọwọ fun ofin to yẹ.

Iroyin naa ni igbesẹ lile awọn eeyan to wa ni agbegbe Badagry keji pẹlu awọn agbegbe miran to wa ni adugbo Ajegunlẹ lo kọkọ saaju, ti wọn si fi ọba le pẹlu lile awọn olugbe adugbo mẹrinlelogun miran to wa ni erekusu Eko.

Image copyright @justempower

"Pẹlu ibanujẹ la fi n wo ijọba apapọ lati ipasẹ ileesẹ ologun oju omi, ti wọn n le awọn eeyan to n gbe ni adugbo Abagbo, Abule Ẹlẹpa, Abule Glass, Ajakoji, Akaraba, Bobukoji, Ebute Oko, Fashola, Idi Mango, Ilajẹ, Inangbe/Ilado, Kopiamy, Ogunfẹmi, Oko-Kate, Okun Alfa, Okun Babakati, Okun gbogba, Okun Ilasẹ, Okun Kobena, Sankin, Sapo Okun ati Tokunbọ, titi de Tarkwa Bay."

"Ẹnu ya wa nipa awijare ileesẹ ologun lori igbesẹ lile awọn eeyan yii, niwọn igba ti wọn mọ pe ko si ofin kankan lorilẹede Naijiria to fi aaye gba igbesẹ wiwo ile awọn araalu tabi fifi iya jẹ wọn lọna to lodi sofin."

Ẹgbẹ Ajafẹtọẹni naa wa n rọ awọn asaaju wa leti pe awọn ilana aatọ wa nilẹ to jẹ itẹwọgba lawujọ agbaye eyi to de sise amojuto agbegbe kọọkan, ti yoo si tun mu agbega ba idagbasoke aabo ati awujọ.

Ìbọn, àfẹ́fẹ́ atajú àti katakata ní àwọn ológun fi lé àwọn olùgbé Tarkwa Bay ní erékùṣù Eko

Image copyright @justempower

Iroyin kan to gba ori ayelujara kan salaye pe awọn ọmọ ologun ti n fi tipa le awọn eeyan to n gbe ni adugbo Tarkwa Bay nilu Eko.

Gẹgẹ bi awọn iroyin to gba oju opo ikansiraẹni Twitter ti wi, awọn ọmọ ologun oju omi, Nigerian Navy lo n le awọn eeyan naa kuro ni agbegbe ọhun to wa ni erekusu ipinlẹ Eko.

Iroyin naa ni lati osu kejila ọdun to kọja, paapa lati ọjọ aisun ọdun Keresi ni awọn ologun ti ya bo agbegbe naa, ti wọn si n le awsn eeyan naa tipa tikuuku.

A gbọ pe pẹlu ọta ibọn, afẹfẹ tajutaju ati ẹrọ katakata ni wọn fi ni ki awọn olugbe agbegbe ọhun kuro ni ibugbe wọn naa.

Image copyright @justempower

Iroyin naa fikun pe awọn ọmọ ologun yii lo n yin ibọn soke soju ofurufu, lati fi dẹru ba awọn olugbe erekusu naa, ki wsn lee tete ko aasa wsn kuro lagbegbe naa.

Wọn ni wakati kan pere ni wọn fun awsn eeyan to n gbe ni agbegbe ọhun lati ko ẹru wọn, eyi to mu ki ohun gbogbo dojuru.

Image copyright @justempower

Lọwọlọwọ bayii, o seese ki erekusu Tarkwa Bay, ti ọpọ eeyan maa n lọ lati gbafẹ lee ma si mọ nitori isẹlẹ to waye yii.

Ìjọba Èkó yóò ṣètò ààbò àti àtúnṣe Abúlé Ẹgba tí iná jó - Igbákejì gómìnà

Image copyright Twitter/drobafemihamzat

Igbakeji Gomina ipinlẹ Eko, Obafemi Hamzat ti ṣe abẹwo sawọn adugbo ti o farakasa iṣẹlẹ ijamba ina lagbegbe'Abule Egba ,nilu Eko.

Lasiko to n ba awọn ara adugbo kẹdun, Hamzat fi ifarajin ijọba han nipa mimu atunṣe ba agbegbe naa ati pipese aabo to peye.

Hamzat to ṣoju fun Gomina ipinlẹ Eko,si wa lara awọn eekan ijọba, to ti ṣe abẹwo si abule Egba lẹyin ijamba ina to ṣakoba fun dukia nibẹ.

Image copyright Twitter/drobafemihamzat

Ẹwẹ, ọga agba ileeṣẹ to n risi ọrọ epo rọbi ni Naijiria, Mele Kyari, naa ti ṣe abẹwo si Abule Egba ti o si ni ileeṣẹ NNPC ti brẹ si nigbe epo gba inu ọpa to gba Abule Egba kọja .

Kyari ninu ọrọ rẹ nibẹ, rọ awọn ara adugbo lati maa ta awọn agbofinro lolobo, bi wọn ba ti ko firi awọn to n bẹ ọpa epo.

Bakanna ni o tun ṣe abẹwo si Oba ilu Eko, Akiolu Rilwan nibi to ti beere iranwọ lọdọ awọn lọbalọba nipa mimu aabo to peye ba awọn adugbo to wa labẹ wọn.

Image copyright Twitter/NNPCgroup