Amotekun: Àwọn èèyàn sọko ọ̀rọ̀ sí Tinubu lórí ìkéde rẹ̀ nípa Amotekun

Aworan FFF ati Bola Tinubu

Ṣaaju ki Asiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress Bola Ahmed Tinubu to sọrọ nipa idasilẹ ikọ alaabo Amọtẹkun, n ṣe lawọn eeyan n dẹti lati gbọ ọrọ rẹ.

Bayi to ti wa fi ọrọ sita, iriwisi ọtọọtọ ti n tẹle ọrọ rẹ tawọn kan si ni o kọ lati soju abẹ niko nipa idasilẹ Amọtẹkun.

Ninu awọn to fi esi sita la ti ri Femi Fani Kayode ti ko pẹ ọrọ sọ rara lati bẹnu atẹ lu Tinubu. Lero tirẹ, Tinubu n gbe lẹyin ijọba apapọ ni:

Fani Kayode nikan kọ ni o lero pe Tinubu ko gbe lẹyin awọn eeyan ilẹ Yoruba.

Dexbrown Civil @Eni_kanda naa sọ pe, Tinubu ko sọ ododo nitori pe o n gbero lati jẹ aarẹ Naijiria.

Ibi kanna ni Òkín Oba Eye@St_michaelalter sun, ti o kọ ori si ibi kanna.

Amọ bi awọn ti ko gba ti ọrọ rẹ ṣe n sọ tiwọn, lawọn miran n kan sara si.

Awọn ta n sọ yi ni agba ki fi gbogbo ẹnu sọrọ ati pe, bi o ti ṣe yẹ ki Tinubu sọrọ lo ṣe sọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ̀yin gómìnà Yorùbá, ẹ gbé òfin kalẹ̀ láti ti Amotekun nídìí, kí àròyé leè dópin - Falana

Ilu ti ko ba si ofin, ẹsẹ ko si nitori naa, ni ilumọọka agba amofin nni, Femi Falana se n ke tantan tan fun awọn gomina lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria pe, ki wọn fi ofin gbe idasilẹ eto Amotekun nidi.

Falana, lasiko to n sọrọ lori ifidimulẹ ikọ alaabo ọhun nilẹ Yoruba kede pe, gbogbo awuyewuye to n waye lori agbekalẹ ikọ Amotekun ko ba ti ri bẹẹ, to ba jẹ pe awọn gomina ti kọkọ se ohun to yẹ ki wọn se ni, nipa sise ofin ti yoo ti ikọ naa lẹyin nipinlẹ koowa wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agba amofin naa wa kesi awọn gomina ilẹ Yoruba pe ko tii pẹ ju bayi, yoo si dara lati tete se awọn ofin naa, lati ipasẹ awọn ile asofin ipinlẹ wọn, ki eto Amotekun lee rẹsẹ walẹ digbin.

"Awọn gomina ilẹ Yoruba sefilslẹ eto alaabo kan ti wọn pe ni Amotekun, ti ileesẹ Ọlọpaa si tii lẹyin amọ agbẹjọro agba nilẹ yi, Abubakar Malami ta ko pe ko bofin mu. Bi o tilẹ jẹ pe mo ni nkan ba Malami fa lori ikede rẹ naa, amọ maa kọkọ rọ awọn gomina ilẹ Yoruba naa lati tete lọ fi ẹsẹ ofin ti agbekalẹ naa nidi."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama

"Nigba ti ko si abala ati ẹsẹ ofin to yẹ fun agbekalẹ eto Amotekun, to fi mọ ilana isọwọsisẹ wọn, ojuse ti wọn yoo se, ilana eto akoso wọn, ipese ati owona, ni ọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lorisirisi nilẹ yii se n tẹsiwaju lati maa sọ ero wọn lori awuyewuye ti ko nidi, eyi to n ti agbekalẹ eto Amotekun nidi."

Bakan naa lo fikun pe, o yẹ ki awọn eeyan ilẹ Yoruba to tẹwọgba eto naa mọ nipa ofin to gbe Amotekun royats si awsn eeyan to n tako.

Àwọn èèyàn tó ń tako ètò Amotekun ni kò ní àròjinlẹ̀ - Tinubu

Image copyright Facebook/Bola Tinubu

Lẹyin o rẹyin, asaaju ẹgbẹ oselu APC ati gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Oloye Bola Ahmed Tinubu ti sọrọ lori eto alaabo Amotekun tawọn gomina ilẹ Yoruba gbe kalẹ.

Bola Tinubu, ẹni to foju han ninu atẹjade kan to fisita pe o n se atilẹyin fun eto Amotekun, wa fikun pe agbekalẹ eto naa ko dunkoko rara mọ ifẹsẹmulẹ orilẹede Naijiria.

Amọ Tinubu ko sai daba pe ki ipade igbọraẹniye wa laarin awọn gomina ẹkun iwọ oorun guusu orilẹede yii ati agbẹjọro agba ni Naijiria, Abubakar Malami lori agbekalẹ eto Amotekun.

Image copyright Bola Ahmed Tinubu

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ tun woye pe "awọn eeyan to ni agbekalẹ eto aabo Amotekun yoo fa isọkan orilẹede Naijiria ya pẹrẹ-pẹrẹ lo jẹ ẹwa ede to lewu lati ẹnu awọn eeyan to yẹ ki oye ye julọ."

"Gbogbo awọn eeyan to n pariwo pe agbekalẹ eto alaabo ti ko mu ewu lọwọ yii , to si tun ni gbedeke ibi to lee sisẹ de lo n dẹru ba isọkan Naijiria ni ko ni arojinlẹ."

Ko tan sibẹ, atẹjade asaaju ẹgbẹ APC naa ni, awọn eeyan to tun n kesi ijọba apapọ lati jẹ gaba, tabi sọ ẹkun guusu Naijiria di akurẹtẹ, lo ti sọnu lai mọ ibi ti wọn n lọ, ti ẹmi ibẹru si ti di oju inu wọn, bẹẹ ni agbara oselu ti kun ọpọlọ wọn ni oorun.

Tinubu afikun pe eyi lewu pupọ, to si lee se orilẹede kan ni ijamba taa ba gba iwa imọtara ẹni nikan laaye lati dagba.

Ko sai tun sọ ero rẹ nipa awọn eeyan to n se atilẹyin fun agbekalẹ eto Amotekun, to si salaye pe ọpọ wọn ni ko ni oye pupọ nipa eto naa, gẹgẹ bi awọn eeyan to jẹ alatako eto naa ko se ni oye nipa rẹ pẹlu.

O ni ọpọ awọn eeyan to jẹ alatako eto Amotekun ni ko tako lori otitọ amọ wọn se bẹẹ nitoripe awọn alatako wọn ninu oselu lo daba eto naa ni, tabi tori pe wọn ko lee ri anfaani kankan jẹ ninu rẹ fun ara wọn ni.

"Ọwọ ti ọpọ eeyan fi mu ọrọ Amotekun yii fihan pe ọna wa si jin ni Naijiria lati mu ki eto iselu ijọba awa ara wa pegede. Ọpọ okun ni awọn eeyan fi sofo lati dabaru eto yii dipo ki wọn wa ọna abayọ si