Oko oloyun: Àwọn agbébọn pa gbajúgbajà apòògùn ìbílẹ̀, Àláájì Fàtáì ọkọ olóyún

Fatai Ọkọ oloyun Image copyright others

Gbajugbaja, oniṣegun ibilẹ, Alhaji Fatai Yusuf ti ọpọ mọ si ọkọ oloyun lawọn eeyan kan yinbọn pa ni irọlẹ Ọjọbọ ni ipinlẹ Ọyọ.

Gẹgẹbi iroyin ṣe sọ, opopona Eruwa si Igboọra lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Ọyọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMercy Aigbe, Lateef Adedimeji, Ayoola Ayolola kó sọ́wọ́ ìbéèrè kàbìtì, ó di gbọin!!!

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Gbenga Fadeyi to fi idi rẹ mulẹ fun BBC news Yoruba ṣalaye pe lootọ ni awọn aṣekupani pa Alhaji Fatai Ọkọ Oloyun ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori rẹ.

'Aṣẹ ti wa lati ọdọ kọmiṣọna ọlọpaa pe ki ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa, SCID bẹrẹ iwadi lori rẹ lati mọ bi iku rẹ ṣe jẹ'.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko tii lee sọ ni pato boya igbenipa ni iku rẹ ni abi nnkan miran. Ayafi nigba ti wọn ba pari iwadii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWasiu Ayinde: Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá

Gbajugbaja oniṣegun ibilẹ ni Alhaji Fatai Ọkọoloyun ti o jẹ ilu mọọka pẹlu awọn ọkan-o-jọkan ogun ibilẹ rẹ eleyi ti o gbajugbja.

Alahaji ọkọ oloyun wa lara awọn eekan to mu iṣegun ibilẹ tọ ọna igbalode lọ nipa ṣiṣe ogun ibilẹ si igo gẹgẹ bii olomi ati ni koro bi awọn ogun oyinbo.

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii ko tii si ẹni lee sọ bi iku rẹ ṣe jẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì!