Amotekun: Omi ṣì ń bẹ làmù fún ìjọba lórí Àmọ̀tẹ́kùn - Amòfin Fẹ́mi Abórìṣàdé

Aworan Amọtẹkun

Awọn gomina ipinlẹ iwọ oorun yoo nilo lati tete jawe sobi lori ipenija to n dojukọ ikọ alaabo Amọtẹkun ti wọn gbe kalẹ.

Amofin Fẹmi Aboriṣade to jẹ ajafẹtọ araalu lo ṣalaye bẹẹ nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori ọna ofin ti awọn gomina yoo lo lati ti Amọtẹkun lẹyin.

Amofin Aboriṣade ṣalaye pe ko le si wahala lati wa ofin fi gbe Amọtẹkun lẹyin ni toripe yoo kan nilo pe awọn awọn ileegbimọ aṣofin ipinlẹ kọọkan o gbe ofin kalẹ ni eleyi ti adehun nnkan ti wọn fẹ ko wa yoo ti di mimọ laarin wọn.

O ni niwọn igba to jẹ pe ileeṣẹ Oodua tilẹ ti wa tẹlẹ laarin awọn ipinlẹ naa, wiwa eto afẹnuko ofin ko lee jẹ ipenija ati pe nigba ti ofin ilẹẹwa ko tii faye ile aṣofin ẹlẹkunjẹkun kalẹ, awsn ile aṣofin ipinlẹ ni iṣẹ ku si lọwọ.

Nigba ti o n dahun ibeere boya ohun ti alaga ajọ gomina ipinlẹ ẹkun iwọ oorun gusu, Gomina Rotimi Akeredolu sọ pe lasiko ti awọn ba fi n ṣeto ofin naa, mimi kan ko lee mi Amọtẹkun, amofin Aboriṣade ni ootọ ọrọ ni Akeredolu sọ nitori pe niwọn igba ti eto kan ko ba tii di iṣọkan ati itẹsiwaju orilẹede Naijiria, a ko lee sọ pe iru eto bẹẹ ko bofin mu.

O fi kun un pe eeyan kan kii fi iṣẹ igbọnsẹ ran ọmọ ẹni nitori naa, kii ṣe ẹṣẹ pe awọn gomina naa ko duro gbe ofin kalẹ ki wọn to gbe Amọtẹkun naa kalẹ gan an gan.

O ni itara ati doola ẹmi kọja ironu ofin kan lo ṣeeṣe ko faa ti awọn gomina naa fi kọkọ gbe igbesẹ ki wọn to lọ yanju ọrọ ofin.

Amọṣa o wa fi kun pe bi o ti wu ki eto abo Amọtẹkun o dara to, bi ijọba ko ba ṣe ohun to tọ loriipese iṣẹ, lile iṣẹ danu, ipese awọn ohun elo amayedẹrun, eto ẹkọ ọfẹ ati bẹẹbẹẹlọ fun araalu, faims ki o ma jẹ oju kan naa ni ẹkun Yoruba yoo ba ara rẹ.