Yoruba Films: Àwọn òṣèré tó bímọ s'Amẹrika lọ́dún 2019 rèé kí Trump tó f'òfin dèé

Ronke Odusanya, Tunde Owokoniran ati Wunmi Toriola Image copyright Instagram

Bi awada, bi ere, ọrọ naa ti di otitọ bayii. Ijọba ilẹ Amẹrika ti kede pe ohun ko ni fawọn ara ilẹ okere ni iwe irinna lati wa bimọ si orilẹede naa mọ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti akọwe iroyin ijọba Amẹrika White House, Stephanie Grisham fi sita, ofin yii ti mulẹ lati oni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni ọdun 2020.

Ọgbẹni Grisham ṣalaye pe igbesẹ yii ṣe pataki lati mu eto aabo ba irinrinajo si ilẹ Amẹrika gbopọn sii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMercy Aigbe, Lateef Adedimeji, Ayoola Ayolola kó sọ́wọ́ ìbéèrè kàbìtì, ó di gbọin!!!

Ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria papaajulọ awọn oṣere ere ori itage lo ti bi ọmọ si ilẹ Amẹrika eleyi to si ti sọ awọn naa ọmọ ilẹ Amẹrika.

Diẹ niyii lara awọn oṣere tiata Yoruba atawọn ilumọọka ọmọ Yoruba miiran ti iyawo wọn bimọ silẹ Amẹrika.

Wunmi Toriola

Ijafara lewu lawọn Yoruba ma n wi. Eyi lo difa fun oṣere tiata Yoruba, Wunmi Toriola bimọ rẹ akọkọ silu Amẹrika lọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa ọdun 2019.

Ọjọ kẹtala oṣu karun un ọdun 2018 ni Wunmi ṣe igbeyawo pẹlu ọkọ rẹ to fi oke okun ṣe ibugbe.

Ọdun kan o le diẹ ni Eleduwa fi ọmọkunrin lanti lanti \ti orukọ rẹ n jẹ Zion jinki idile wọn ti wọn si di ọlọmọ.

Ronke Odusanya

Lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni Ronke Odusanya kede loju opo Intsagram rẹ pe Ọlọrun fi ọmọ jojolo ta oun ati ọkọ oun lọrẹ.

Ilu Amẹrika loun naa bimọ si, kete to kede lori ayelujara lọgọrọ awọn oṣere ẹgbẹ rẹ bẹrẹ si ni fi ikinni ranṣẹ sii.

Ronke sọ lori oju opo Instagram rẹ pe inu oun ko le sọ bi inu oun ṣe dun to lori ọmọ tuntun ti Eleduwa fi ta idile oun lọrẹ.

Tunde Owokoniran

Oṣere tiata Tunde Owokoniran ati iyawo rẹ ki ọmọjojolo kaabọ si ẹbi wọn lọjọ kejidinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2019 lorilẹede Amẹrika.

Tunde gangan an lo fi aworan rẹ ati aya rẹ pẹlu ọmọ wọn si ori oju opo Twitter.