Amotekun: Àwọn gómìnà ìpínlẹ́ ẹkùn ilẹ̀ Yorùbá yoó ṣì ṣèpàdé pẹ̀lúu Ààrẹ Buhari lórí 'Àmọ̀tẹ́kùn'

Awọn gomina ẹkun Yoruba n sepade pẹlu Igbakeji Aarẹ lori Amotekun Image copyright Tolu ogunlesi

Ọrọ taa ni ki baba o maa gbọ, baba ni yoo pari rẹ ni ọrọ Amọtẹkun tun kan bayii gẹgẹ bii alaga ajọ awọn gomina ẹkun ilẹ Yoruba, Gomina Rotimi Akeredolu ṣe sọ.

Akeredolu ni awọn yoo ṣi ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lori awọn awuyewuye to n waye ati agbekalẹ eto ikọ alaabo ilẹ Yoruba ti wọn pe ni 'Amọtẹkun'.

Akeredolu to jẹ gomina ipinlẹ Ondo ṣalaye pe irinajo aarẹ si ilẹ Gẹẹsi lo jẹ ki wọn sun ipade naa, bibẹẹkọ, ọsẹ to kọja lọ ni o yẹ ko ti waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMercy Aigbe, Lateef Adedimeji, Ayoola Ayolola kó sọ́wọ́ ìbéèrè kàbìtì, ó di gbọin!!!

O fi kun un pe ipade ti awọn ṣe pẹlu Igbakeji aarẹ, Yẹmi oṣinbajo ko ṣaadede waye o. O ni aarẹ Buhari gan gan lawọn kọwe si lati ri ki aarẹ to wi pe oun n lọ si ilẹ okeere lati ṣe awọn ohun kan tabi meji, ṣugbọn ki oun ma baa fi ti oun da wọn duro lo fi ni ki awọn gomina ilẹ Yoruba ọhun lọ ṣepade pẹlu igbakeji oun.

Gomina Akeredolu ni o da oun loju pe aarẹ yoo tẹti gbọ ero ati ẹhonu awọn gomina ẹkun ilẹ Yoruba naa.

O ni Aarẹ Buhari ko fi igba kankan tako agbekalẹ ikọ alaabo Amọtẹkun, ṣugbọn ariwo tawọn kan pa lẹyin ọrọ ti amofin agba Abubakar Malami sọ lomu ko tara kiji pe bawo lo ṣe jẹ.

Ẹ̀yin obìnrin tẹ́ẹ fẹ́ wá bímọ ní America, ọ̀nà ti tì pa látònì! - Trump

Cisse bẹ́ sí Kàǹga nítori fóònù N3,000

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì!