EKSU: Àwọn òṣìṣẹ́ tí fásitì EKSU lé fún ìgbìmọ̀ aláṣẹ ní gbèdéke ọgbọ̀n ọjọ́ láti dá wọn padà sí ẹnu iṣẹ́

iloro ọgba fasiti EKSU nilu Ado Ekiti Image copyright others

Awọn kan lara awọn oṣiṣẹ fasiti ipinlẹ Ekiti, EKSU nilu Ado Ekiti ti iṣẹ bọ mọ lọwọ laipẹ yii ti fariga pe akutupu yoo hu o bi awọn alaṣẹ fasiti naa ko ba da awọn pada sẹnu iṣẹ wọn laarin ọgbọn ọjọ.

Awọn oṣiṣẹ naa wa lara awọn oṣiṣẹ bii ẹẹdẹgbẹrun ti wọn yọ niṣẹ lọgba fasiti ọhun ni oṣu kejila ọdun to kọja.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi yọ awọn oṣiṣẹ naa ni ayederu iwe ẹri, aitọ ọna to tọ wọ iṣẹ, kikọja ọjọ ori ti ofin la kalẹ lati ṣiṣẹ ni fasiti atawọn ẹsun miiran eyi to tako ilana igbanisiṣẹ.

Ninu lẹta kan eleyi ti agbẹjọro wọn kọ, awọn oṣiṣẹ naa ni bi wọn ṣe gba iṣẹ lọwọ awọn tako ilana ati ofin iṣẹ ijọba.

Lẹta naa darukọ awọn oṣiṣẹ mẹta...ti wọn ni wọn n gbẹnu awọn oṣiṣẹ mọkandinlọọdunrun miran ti wọn gba siṣẹ ni ọdun 2016 pe ẹjọ ọhun ki wọn to yọ wọn niṣẹ ni ọjọ karun un oṣu kejila ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMercy Aigbe, Lateef Adedimeji, Ayoola Ayolola kó sọ́wọ́ ìbéèrè kàbìtì, ó di gbọin!!!

Awọn amofin to n gba ẹjọ wọn ro ṣalaye pe ṣaka lara ilana to gba awọn eeyan ọhun siṣẹ le eleyi to tako ohun ti o n lọ kaakiri.

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ naa tun n beere fun sisan gbogbo owo oṣu, ẹtọ ati ajẹmọnu to tọ si wọn lati igba ti wọn ti yọ wọn kuro niṣẹ titi di asiko yii.

Related Topics