Mushin Amu Market fire: Ibi táa ti ń rí oúnjẹ òòjọ́ wa nìyí o, ẹ gbà wá

Mushin Amu Image copyright Twitter

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko ti fi aridaju han pe lootọ ni ina burẹkẹ ni isọ pako ni Mushin Amu ṣugbọn wọn ni awọn oṣiṣẹ awọn ti wa nibẹ.

Alukoro ajọ LASEMA, Ọgbẹni Nosa Okunor sọ fun BBC pe nkan bii ago kan kọja lọganjọ oru ni ina yii ti bẹrẹ si ni jo ti awọ́n si ti n gbiyanju lati pa a.

Ọ̀gbẹ́ni Nosa ni awọn ṣi wa lori igbiyanju lati mu ki ọwọ ina naa rọlẹ ṣugbọn "nitori pe asiko ẹrun ati ọgbẹlẹ niyii ati pe ọpọlọpọ nkan to lee tete ran ina ni wọn ko sinu awọn ṣọọbu to wa ninu ja naa, a ko tii ri i yanju".

Image copyright LASEMA

Inu iroyin ibanujẹ yii ni awọn olugbe agbegbe Mushin ni ipinlẹ Eko ji si ni owurọ yii ni nkan bii ago kan oru kọja iṣẹju marundinlọgbọn ti ọpọlọpọ ipe si ti lọ si ọdọ ajọ LASEMA.

Iroyin ti aj LASEMA fi ranṣẹ ni pe kete ti ipe de ọdọ awọn naa ni wọn ti kan lu iṣẹ. Nigba ti wọn de ibi iṣẹlẹ naa, wọn ri i pe ọgọọrọ ile itaja pako ati awọn ileegbe ni ina naa ti ran mọ.

Nigba ti wọn ṣe iwadii siwaju sii, wọn gbọ pe awọn nkan amuna wa lo fa iṣẹlẹ ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii le sọ pato iye nkan to ti bajẹ bayii titi di igba ti wọn yoo ri aridaju akọsilẹ, wọn fi iwoye ṣiro pe ina yii ti ba ohun ini ati ja to to ọpọlọpọ miliọnu naira jẹ.

Ẹwẹ, ko si iroyin pe ẹmi kankan ba iṣl naa rin ko si si ẹni to fara pa bo tilẹ jẹ pe awn oni jagidijagan kan fẹ maa da wahala silẹ latari iranwọ aibere fun ti wọn fẹ maa ṣe.

Lọwọlọwọ, akitiyan ti n lọ lati pa ina naa patpata pẹlu iṣẹ ẹka panapana ajọ LASEMA pẹlu ọkọ apina meji wọ, ati ẹka panapana ileeṣẹ Julius Berger naa pẹlu ọkọ apina meji ati ọkọ nla olomi.

Bakan naa, wọn ni ileeṣẹ panapana ti ipinlẹ Eko naa wa nibẹ pẹlu ọkọ apina meji ati pe ajọ RRS, LNSC atawọn araalu ni gbogbo wọn n pawọ pọ lati ṣeranwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOyo Fire: Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

Ẹwẹ, loju opo ayelujara, awọn eeyan ti gba gbogbo rẹ kan ti wn si n ke gbajare lori anfani ti awọn ati mọlẹbi wọn n ri ni ọja nla yii bẹẹ si lawọn araalu n gbohun adura soke si Ọlọrun.

A ó máa mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn yìí wá fún un yín.