Lassa Fever: 'Ẹ yé mu gaàrí mọ́, tẹ́ẹ̀ bá fẹ́ lùgbàdì ibà Lassa'

Ekute ninu gARI Image copyright OTHERS
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ ènìyàn lo ti sọ ẹmi nù nítorí àìsàn Iba Lassa

O dabi ẹni pe alabọrun ti n di ẹwu bọ o pẹlu iba Lassa to ran kaakiri bi ina inju ọyẹ lorilẹede Naijiria.

Oludari ẹka eto ilera nipinlẹ Enugu, Dokita Boniface Okolo ti awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ye mu gaari mọ ti wọn ko ba fẹ lugbadi iba Lassa.

Dokita Okolo sọ pe awọn eku to n fa aarun Lassa ti maa n fara kan ọpọ ounjẹ to wọ pọ ju tawọn eeyan n jẹ ni Naijiria, gaari lọpọ igba.

Okolo ni mimu gaari lewu pupọ nitori kokoro to n fa iba Lassa le wa ninu gaari.

Dokita Okolo ni ewu to wa ninu gaari mimu ni pe lai si omi gbigbona to le pa kokoro iba Lassa, aifaimọ ki eeyan maa lugbadi aarun ọhun.

O ni ko si ewu pẹlu ki eeyan fi gaari tẹ ẹba nitori omi gbigbona ni yoo pa kokoro to le fa iba Lassa ninu gaari.

Ẹwẹ, iroyin to tẹ wa lọwọ lo sọ pe iba Lassa ti wọ ipinlẹ Kaduna bayii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ekute to n fa iba Lassa pọ ni Iwọ-oorun ilẹ Africa.

Kọmiṣọnna fun eto ilera nipinlẹ naa, Dokita Amina Mohammed-Baloni lo fidi ọrọ naa mulẹ pe ijọba ibilẹ Chikun ni akọsilẹ ti wa ẹni kan ti lugbadi aarun naa.

Dokita Mohammed-Balonim sọ pe ọkunrin to lugbadi aarun naa, ẹni ọdun mẹrindinlogoji ti n gba itọju lọwọ bayii nile iwosan ti ijọba ti ya sọtọ fun itọju awọn to ni iru aarun bẹẹ.

Kọmiṣọnna rọ awọn eeyan ipinlẹ Kaduna lati mu eto imọtoto lọkunkundun lati le dena iba Lassa.