Minimum wage: Ìjọba Ondo gbà láti san #30,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ

Gomina Rotimi Akeredolu Image copyright Faceboo/Rotimi Akeredolu Aketi

Ẹrin keekee ti gba ẹnu awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo bayii lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa gba lati san ẹgbẹrun un lọna ọgbọn naira

gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ fawọn oṣiṣẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ ifọrọwerọ laarin ijọba ipinlẹ Ondo ati ẹgbẹ oṣiṣẹ lapaapọ, ijọba ti kede pe ohun ti ṣetan lati san owo naa.

Ọjọ Satide ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kinni ọdun 2020 ni ijọba atawọn oṣiṣẹ tun jọ ṣepade pọ lati yanju ọrọ naa.

Bakan naa awọn aṣoju ile igbimọ aṣofin ati ẹka eto idajọ nipinlẹ Ondo naa wa nibi ipade ọhun.

Ijọba gba lati san owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ to wa ni ipele kẹfa lọ si isalẹ nigba ti awọn oṣiṣẹ to wa lati akasọ keje lọ soke yoo j'anfaani ẹkunwo ti wọn naa.

Ninu ọrọ tiẹ, olori ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Oluwadare Aragbaye dupẹ lọwọ awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ fun ifọwọsowọpọ wọn, o ni ijọba yoo tẹsiwaju latiu mu igbayegbadun awọn oṣiṣẹ lọkunkundun nipinlẹ naa.

Awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ naa gboriyin fun ijọba Gomina Rotimi Akeredolu lori bi o ṣe n sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ ati ajẹmọnu wọn deedee lati ọdun 2017.