Human trafficking: Iṣẹ́ irun ṣíṣe ló di iṣẹ́ aṣẹ́wó mọ́ Adeola lọ́wọ́ ní Cote D'ivoire

Ijinji Adeọla, (kii ṣe orukọ abisọ rẹ) ilepa atidagbasoke ati atila laye lo fọkan si ko to di pe irinajo ẹda jaa ni tanmọọ.

Iṣẹ aje lo ba lọ soke okun labẹ Ẹtan pe yoo lọ kọ iṣẹ yoo si ko ẹru ati ẹru wale ṣugbọn nigba to de orilẹede Cote d'Voire ni o to han si pe iṣẹ aṣẹwo ni wọn mu oun wa ṣe.

Adeọla mu ẹnu le oniruuru oun ti oju oun atawọn ọdọbinrin ọmọ orilẹede Naijiria miran n ri lori owo nọbi ti wọn n fi wọn ṣe ni ilẹ okeere.