Lassa fever outbreak: Ìpínlẹ̀ Ondo, Edo àti Ebonyi ni ibà Lassa ti ń ṣọṣẹ́ jùlọ

Awọn onimọ iṣegun n yẹawọn oogun kan wo Image copyright @NCDCgov

Ajọ to n mojuto ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti kede pe eeyan mọkandinlogun lo ti di alaisi lori ajakalẹ arun iba Lassa to tun ṣẹṣẹ gbilẹ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria.

Ipinlẹ mọkanla lo ni arun iba Lassa ti tan kalẹ de lorilẹede Naijiria ti wọn si ti ri igba o din marun un eeyan ti ọwọ aarun naa si ti ba.

Ninu atẹjade kan, ti ọga agba ajọ naa, Dokita Chikwe Ihekweazu fi sita, ipinlẹ Ondo, Edo ati Ebonyi ni ọwọja arun yii pọ si julọ.

O ni ida mọkandinlaadọrun iye awọn ti o ti ko aarun naa ni wọn wa lati ipinlẹ mẹta yii.

Ẹ lee maa wo pe ki lo n fa a ti arun yii tun fi pada wa ni iru akoko bayii? Ajọ NCDC ni bi oju ọjọ ati ayika ṣe ri lasiko yii lo faa ati pe ajs naa n sa gbogbo ipa to yẹ lati kapa rẹ.

Ajọ naa ṣalaye pe ọpọ awọn oṣiṣẹ ni wọn ti fi ṣọwọ sawọn ipinlẹ marun un to n fara ko arun ọhun ni lọwọlọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHepatitis: A kò leè kóo nípa dídìmọ́ ara ẹni

Amọṣa, ajọ naa ni adinku ti ba iye ẹmi to ba aisan yii lọ bi a ba wo o ni ifẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu ọwọja rẹ lasiko yii kan naa ni ọdun 2019.

Ida mẹtalelogun awọn eeyan to ko aisan iba Lassa lọdun 2019 lo baa lọ sọrun alakeji, ṣugbọn lọdun yii nkọ, ida mẹrinla awọn to ko aisan naa ni wọn jade laye.

Oludari agba Ajọ to n mojuto ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, naa ni ibudo ayẹwo marun ọtọọtọ lo wa lorilẹede Naijiria nibiti wọn ti lee ṣayẹwo iba Lassa.