Coronavirus: Àjọ tó ń rí sí ìwọléwọ̀de ní kò s'áàyè f'ẹ́nikẹ́ni tó láárùn yí láti wọlé sí Nàìjíríà

Awọn arinrin ajo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n ri si wiwọlẹ ati jijade si orilẹede Naijiria sọ pe digbi lawọn wa lati dena aarun Coronavirus to n ran kaakiri agbaaye.

Agbẹnusọ fun ajọ naa to ba BBC Yoruba sọrọ, James Sunday ṣalaye pe ajọ to n ri si wiwọle ati jijade lati Naijiria ko ni gba ẹnikẹni to ba laarun Coronavirus laaye lati wọle.

Ọgbẹni Sunday sọ pe ko si ohun ti ajọ naa n lo ju ofin to wa nilẹ lọ lori jijade ati wiwọle si orilẹede Naijiria.

O fikun ọrọ rẹ pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa ko fẹ lugbadi aarun coronavirus, eyi lo jẹ ki wọn wa ni igbaradi.

Agbẹnusọ fun ajọ naa ṣalaye siwaju sii pe ọrọ yii kọja ọrọ Naijiria nikan, o ni gbogbo orilẹede lo yẹ ki wọn maa ṣe ayẹwo awọn arinrinajo finifini ki wọn to jẹ ki wọn wọn ọkọ ofurufu lọ si orilẹede mii.

Ọgbẹni Sunday ni ojutu si ọrọ aarun Coronavirus ni pe ki orilẹede kọọkan sẹ eto ayẹwo to mọyan lori eyi ti yoo dena awọn to laarun naa lati maa le rinrin ajo jade silẹ miiran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ, ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, Thoracic lọ sọ pe o ṣeeṣe ki ewu aarun Coronavirus wu orilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita, wọn ni Naijiria le wa ninu ewu nitori ọpọ oniṣowo lo wọ Naijiria lati China ti aarun naa ti bẹrẹ.

Ileeṣẹ to n ri si eto ilera lorilẹede Naijiria ni pẹlu ajọṣepọ ajọ agbaye to n ri si eto ilera WHO, Naijiria ti ni ibudo to lee kapa ṣiṣe ayẹwo ẹni to ba ko aarun aṣekupani Coronavirus eyi to bẹrẹ lorilede China.

Minisita wa loju opo itakun Twitter wọn lati funpe si ẹnikẹni lorilede Naijira to ti lọ si China ni oṣu bii melo sẹyin lati "ya ara wọn s'ọ́tọ̀ na fun ọjọ́ mẹ́rìnlá ki wọn si pe ajọ to nṣamojuto kikoju aarun NCDC lori nọmba 07032864444.