Coronavirus: Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Afíríkà kan tí lùgbadì ààrùn Coronavirus

Awọn eleto ilera

Fasiti Yangtze ni China ti kede pe akẹkọọ kan to jẹ ọmọ ilẹ Afirika ní orilẹede China, Kem Senou Pavel Darly ti lugbadi aarun Coronavirus o si ti wa nile iwosan.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Fasiti naa fi sita, wọn ni akẹkọọ naa lọ si ile iwosan lọjọ kkandinlogun oṣu kinni nigba to kuro ni Jingzhou.

Wọn ri i pe akẹkọọ naa ni aisan iba, ikọ, igbẹ gbuuru bẹẹ si ni ẹsẹ rẹ ko lagbara pupọ nigba ti wọn ṣe ayẹwo fun un ni ile iwosan.

Latari eyi ni wọn ṣe gbagbọ ti wọn si kede pe o ni aarun Coronavirus lẹyin ọjọ meji ti fasiti naa si ṣa gbogbo ipa wn lati bu ẹrin sẹkẹ r ati ẹbi rẹ ati ọfiisi orilẹede Cameroon ni China.

Ni bayii, ọmọ ọdun mọkanlelogun naa til le jẹun, ara rẹ si wa ni ipo to dara to si balẹ.

Nigba ti wọn ṣawari aarun yii lara rẹ, ti fasiti naa si kede, wọn kọ lẹta si aarẹ Biya ti Cameroon pe ko ran wọn lọwọ.

Image copyright Getty Images

Ọwọ Gómìnà Makinde làṣẹ wà bóyá a ó fí òfin dé Okada ní Oyo -OYRTMA

A kò ní jẹ́ k'ẹnikẹ́ni tó láàrùn Coronavirus wọlé sí Nàìjíríà- Àjọ tó ń rí sí ìwọléwọ̀de

Ìyàwó ilé lu ọmọ ọkọ rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Ogun

'Ẹ bá wa sọ fún Sanwoolu kó dárí jì wá o, ìpinú tí wọ́n ṣe l'Eko kò m'ọ́gbọ́n wá rárá'

O to ọọdunrun ọmọ Cameroon to jẹ akẹkọọ ati oṣiṣẹ ni China to ti funpe si aarẹ Biya ko naw iranwọ si wọn ni ti jijẹ, iboju, ọṣẹ ati pe ko pese nọmba ti wn le tete pe si.

Idi ti orilẹede Cameroon fi kọ lẹta yii si aarẹ Biya ni pe wọn ni awọn ti gbiyanju titi lati kan si ọfiisi wọn to wa ni Beijing ṣugbn to n bọ si pabo.

Ni bayii, awọn akẹkọọ to wa ni ilu Wuhan-Hubei ni ẹru ọjọ iwaju wọn n ba bayii tori wn ko ribi kan si ọfiisi wọn to wa ni China fun iranwọ.

" O n da omi si wa lọkan bi a ba n ri awọn ọmọ orilẹede mii ti wọn n ri iranwọ gba lati ilu wọn. ni bayii, a n wo o bii pe orilẹede tiwa ti pa wa ti.

Ẹwẹ, ijọba ilẹ Cameroon ti sọrọ pe awọn n foju si awọn eniyan wọn to wa ni China bẹẹ si ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹnu ki wọn lee wo ohun ti wọn lee ṣe.

'Street Gospel' tí mò ń kọ, Ọlọ́run ń fi tún ayé àwọn 'Boys' ṣe gan - Testimony Jaga

Related Topics