Revolution Now: Iléẹjọ́ ṣún ìgbẹ̀jọ́ síwájú di ọ̀la Ọjọ́bọ

Omoyele Sowore ati Bakare ti wọn dijọ n jẹjọ Image copyright @YeleSowore

Ileẹjọ giga ilu Abuja ti pasẹ fun agbẹjọro ijọba apapọ ilẹ wa lati san ẹgbẹrun lọna igba naira, owo gba, ma binu fun asaaju ikọ Revolution Now, Omoyele Sowore.

Adajọ Ijeoma, to n gbọ ẹjọ naa kede pe oun pasẹ bẹẹ nitori idaduro ti wọn fun Sowore lori ẹjọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi ni pe ni kete ti adajọ joko lati gbọ ẹjọ ọhun lọjọru ni agbẹjọro ikọ olupẹjọ dide lati sọ fun ile ẹjọ pe agbẹjọro agba nilẹ wa ti gba akoso ẹjọ naa, to si fẹ se atunse si awọn ẹsun ti wọn fi kan Omoyele Sowore.

Image copyright @YeleSowore

O ni oun ko tii fi igbesẹ naa to agbẹjọro Sowore leti, ti oun si nilo akoko lati se bẹẹ, sugbọn adajọ fọnmu pe lati osu kejila ọdun to kọja, eyi to to ọsẹ meje gbako, ti wọn ti so ẹjọ ọhun rọ lo yẹ ki wọn ti fi ọrọ naa to gbogbo ẹni to yẹ leti.

Image copyright @YeleSowore

N kò ní òmìnira, ìjọba Buhari ń tẹ ẹ̀tọ́ mi mọ́lẹ̀ - Sowore figbe bọnu

"Ọsẹ meje ti kọja ti ikọ olupẹjọ ko si fi igbesẹ tuntun nipa ẹjọ naa to awọn igun to yẹ leti. O dabi ẹni pe ẹ ko setan lati bẹrẹ igbẹjọ, tẹ kan fẹ maa fi akoko sofo nitori ofo lasan ni gbogbo awawi yin."

Image copyright @YeleSowore

Adajọ Ijeoma fikun pe nitori idi eyi, wọn gbọdọ san ẹgbẹrun lọna igba naira fun igun olujẹjọ nitori gbogbo aaye ti ofin fi silẹ fun wọn lati sun ẹjọ siwaju ni wọn ti lo tan.

Lẹyin eyi ni adajọ naa wa sun ẹjọ ọhun siwaju di Ọjọbọ ọla, ọjọ Kẹtala osu Keji ọdun 2020.

Image copyright @yeleSowore

Ẹwẹ, loju opo Twitter rẹ, @YeleSowore, asaaju ikọ Revolution Now naa ni oun ti pada de lati ile ẹjọ̀, ti ohun ko si ni ohun toun fẹ jabọ ju iwa ifiyajẹni lọ. Wọn wa sile ẹjọ lai gbaradi, ti wọn si n se atunse si awọn ẹsun .

N kò ní òmìnira, ìjọba Buhari ń tẹ ẹ̀tọ́ mi mọ́lẹ̀ - Sowore figbe bọnu

Saaju lati mu iroyin wa fun yin pe, Omoyele Sowore tii se asaaju ikọ Revolution Now, to n pe fun ijijagbara araalu lorilẹede Naijiria, ti kede pe oun ko tii ni ominira rara.

Soworẹ, ẹni toyọju sile ẹjọ laarọ Ọjọru fun ibẹrẹ igbẹjọ rẹ nile ẹjọ giga ilu Abuja salaye fun BBC Yoruba pe awọn eeyan kan labẹ ijọ apapọ ilẹ wa lo n tẹ ẹjọ oun loju mọlẹ.

Assaju ikọ Revolution Now naa ni se ni wọn n fẹsẹ tẹ ẹtọ oun loju mọlẹ , ti oun si setan lati daabo bo ẹtọ oun.

Nigba toun naa n salaye fun BBC idi to fi tẹle Soworẹ wa sile ẹjọ, Asofin agba kan, to tun jẹ ajafẹtọẹni, Shehu Sani kede pe ọrẹ, arakunrin ati alabasepọ oun ninu isẹ ijija gbara ni Soworẹ.

Sani ni gbogbo iwa ijẹgaba ti Sowore ti n ja fun lati ọjọ pipẹ wa, lo wa n pada jiya labẹ rẹ yii, to si se ni laanu pe o ti ja fun ijọba tiwa n tiwa ju pe ko foju wina ifiyajẹni bii eyi lọ.

"Asiko yii lo yẹ ki gbogbo wa sugba Soworẹ, ka duro tii gbagbagba, ka si ba pin ninu isoro to n la kọja lati ọwọ awọn alagbara. O si ti le ni ọgbọn ọdun taa ti jọ n se pọ, mo si wa pẹlu rẹ ninu ẹmi, ọkan ati ara."

Shehu Sani fikun pe wọn sẹsẹ gba oniduro oun tan lọwọ ajọ EFCC ni gẹgẹ bi wọn se gba oniduro Sowore lọwọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, awọn si gbọdọ fi imọ se ọkan.

Wole Soyinka, Shehu Sanni tẹ̀lé Omoyele Sowore lọ sílé ẹjọ́ fún ìbẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ ẹ̀ṣùn ìdìtẹ̀ gbàjọba

LaarọỌjọru oni la mu iroyin wa pe igbẹjọ agbatẹru ipolongo #RevolutionNow Omoyele Sowore bẹrẹ ni ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja.

Omoyele Sowore, to fi igba kan du ipo aarẹ Naijiria ati akẹgbẹ rẹ Olawale Bakare, ni ijọba Naijiria dijọ fi ẹsun kan pe, wọn n pe fun ifitẹgbajọba Naijiria.

Yatọ si ẹsun yii, wọn tun ni wọn n fọna ẹburu gba owo, ti wọn si tun n dunkoko mọ awọn eeyan loju opo ayelujara.

Awọn mejeeji ti ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn

Yatọ si ẹsun yii, wọn tun ni wọn n fọna ẹburu gba owo, ti wọn si tun n dunkoko mọ awọn eeyan loju opo ayelujara.

Awọn mejeeji ti ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Adajọ Ijeoma Ojukwu ni yoo dari ẹjọ naa.

Wahala laarin ijọba ati Sowore bẹrẹ ni oṣu kẹjọ dun 2019, nigba ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria mu pe o n ṣagbatẹru iwọde jakejado Naijiria.

Lọjọ keji oṣu Kẹjọ ni Sowore fi ọrọ sita loju opo Twitter pe ''A ni lati ṣe ijijagbara eyi tawọn eeyan ti ara n ni yoo fi mu ọjọ ti wọn yoo fi gba ominira, ti wọn ko si ni gba ki awọn amunisin maa fi iya jẹwọn''

Ọjọ keji ni awọn DSS wa mu pe o fẹ tu ijọba aarẹ Buhari ka.

Wọn fi Sowore si ahamọ titi di oṣu Kẹwa ọdun 2019 ti ile ẹjọ paṣẹ ki wọn gba oniduro rẹ leleyi ti awọn agbofinro si kọ lati tu silẹ.

Ọrọ tun gba ọna miran yọ nigba ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria tun gbe ninu ile ẹjọ, lẹyin wakati mẹrinlelogun ti wọn tu silẹ.

Iwa ti awọn DSS hu yi mu ki awọn eeyan bẹnu atẹ lu wọn ni Naijiria ati lẹyin odi.

Lọjọ aisun ọdun Keresi to kọja, agbẹjọro agba Naijiria, Abubakar Malami fi atẹjade sita pe, awọn ṣetan lati tu Sowore ati akẹgbẹ rẹ silẹ ni ibamu pẹlu aṣẹ ile ẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsogbo Photographer:

Yiyọju si ile ẹjọ loni ni igba akọkọ ti wọn yoo bẹrẹ igbẹjọ ẹsun ti wọn fi kan ni pẹrẹwu niwaju adajọ.