Sunday Igboho: N kò le máa gbé ní Soka, káwọn ọmọ onílẹ̀ máa yọ awọn èèyàn mi lẹ́nu

Sunday Igboho Image copyright Sunday Igboho

Ọrọ di boo lọ, ko yago fun mi ladugbo Soka nilu Ibadan lasiko ti gende meji to gbe ohun ija oloro lọwọ, ti wọn pe ara wọn ni ọmọ onilẹ ya bo agbegbe naa.

Owurọ ọjọ Isẹgun ana niroyin gba igboro Ibadan kan, tawọn eeyan si n pe sori redio gbogbo nilu naa pe ẹmi awọn eeyan to n gbe ladugbo naa ko de tori awọn gende agbebọn to ya bo wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A gbọ pe se ni iro ibọn n dun lakọ-lakọ, tawọn eeyan si n sa asala fun ẹmi lasiko ti awọn ọmọ onilẹ ọhun ni ki awọn onile gbe ile wọn kuro lori ilẹ awọn.

Se lawọn ọmọde ati agba, alaboyun ati awọn iyalọmọ, to fi mọ awọn arugbo n sa asala fun ẹmi wọn, ti awọn to si laya lati beere pe ki lo fa isẹlẹ naa, jẹ ajẹkun iya.

Image copyright Sunday Igboho

Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ salaye pe ọpẹlọpẹ asaaju ọmọ Yoruba kan, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho to tete de sadugbo ọhun lasiko ti laasigbo naa gbona janin-jani.

A gbọ pe Igboho ati ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ Babatunde Arowolo, ti gbogbo eeyan mọ si Bako, lo de lasiko lati gba awọn eeyan adugbo naa silẹ, ni kete ti aawọn ọmọ onilẹ naa si foju gaani rẹ, ni wọn ba juba ehoro.

Sunday Igboho, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe, lootọ ni oun lọ si adugbo Soka lana lati gba awọn eeyan adugbo naa silẹ lọwọ ijẹgaba awọn ọmọ onilẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

O ni ni kete tawọn ọmọ onilẹ foju kan oun ati Bako ni wọn fẹsẹ fẹ, eyi to mu kawọn doola ofo ẹmi ati dukia ti ko ba waye latipasẹ isẹlẹ yii.

"Adugbo Soka nilu Ibadan ni mo n gbe, ti awọn agbegbọn kan si ya wọ adugbo mi lati maa dunkoko mọ awọn eeyan mi, n ko si lee la oju mi silẹ, ki n wa larọwọto, kawọn eeyan kan maa se awọn eeyan mi lese tabi pa wọn ni ipakupa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsogbo Photographer:

Bakan naa ni Igboho ni o ti to ẹẹmẹfa ti awọn ọmọ onilẹ naa ti ya bo awọ̀n eeyan adugbo naa, ti wọn si n yinbọn ti wọn n pa awọn mẹkunnu, ti ọpọ wọn si ti ku lai jale, to si n beere pe se gbogbo mẹkunnu lo ni owo lọwọ lati tun ilẹ ra.

Awọn ara adugbo naa ti wa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati tete da si ọrọ naa tori kii se igba akọkọ ree ti awọn ọmọ onilẹ yoo wa maa dun mahuru-mahuru mọ wọn lori ilẹ ti wọn ti ra lati ọdun gbọọrọ.

Gẹgẹ bi iroyin naa ti wi, nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi lati gbọ tẹnu rẹ, o ni ka pe oun pada laipẹ.