Sunday Igboho: Alukoro ọlọ́pàá Ọyọ ní àwọn ọlọ́pàá kọ́ ló kọlu aráàlú, iṣẹ́ wọn ni wọ́n ń ṣe

Awọn Ọlọpa loju popo ati Sunday Igboho Image copyright Instagram/Sunday_igboho

Ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ọyọ ti salaye ohun to mọ nipa rogbodiyan to waye ladugbo Soka lọjọ Isẹgun eyi to pagidina alaafia ilu.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, alukoro fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi salaye pe ohun to mu ki awọn ọmọ onilẹ lọ si adugbo Soka lọjọ naa ko sẹyin ilakaka wọn lati fidi idajọ ileẹjọ to ga julọ mulẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fadeyi ni awọn ọlọpa to wa nibi isẹlẹ naa lo tẹle akọwe ileẹjọ to tẹle awọn eeyan ti wọn pe ni awọn ọmọ onilẹ lọ si adugbo naa, lati ri pe asẹ ileẹjọ fidi mulẹ, kii si se pe awọn ọlọpa naa n gbeja awọn ọmọ onilẹ.

Image copyright Others

Eyi si lo tako iroyin to n ja rainrain nilẹ kiri pe, awọn ọlọpa to le ni ọọdunrun niye, to tẹle awọn ọmọ onilẹ meji naa, to fẹ wa gba ilẹ wọn, lo n fiya jẹ awọn ara adugbo Soka yii, ti wọn fi n sa kijokijo kiri.

Alukoro ileesẹ ọlọpa ni asiko ti akọwe ileẹjọ ati awọn ọmọ onilẹ fẹ se amusẹ idajọ ileẹjọ to da wọn lare, lawọn eeyan kan to pe ni 'Janduku' jade sita si wọn, ti wọn si kọlu wọn, eyi to mu ki laasigbo waye nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Radio Day: Àwọn òṣìṣẹ́ rédíò ní àwọn ń pa ìsòro àwọn mọ́ra ni láti mú inú aráàlú dùn

Fadeyi wa fidi rẹ mulẹ pe Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Ọyọ ti pasẹ pe ki iwadi bẹrẹ lọgan lori ohun to fa rogbodiyan to waye lagbegbe Soka ọhun, ni kete ti iwadi naa ba si ti pari lawọn yoo kede fun araye gbọ.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Isẹgun ni iroyin gbalẹ kan pe awọn ọmọ onilẹ meji ti n pagidina omi alaafia lagbegbe Soka, ti awọn ara adugbo ibẹ si n sa kijokijo kiri.

Iroyin naa ni ọpẹlọpẹ asaaju Yoruba kan, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igbohoati ẹnikeji rẹ, Bako, to gba wọn silẹ lọwọ wahala naa.

Nigba to si n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Igboho ni lootọ loun dide lati gbeja awọn eeyan oun ladugbo Soka,nitori adugbo naa ni oun n gbe, ikọlu awọn ọmọ onilẹ si awọn mẹkunnu to wa nibẹ si ti n di lemọlemọ bayii.