Bayelsa Guber update: Atiku ní àwọn adájọ́ fihàn pé ọwọ́ aráàlú lagbára sì wà

Atiku Abubakar ati Sẹnẹtọ Douye Dirini Image copyright Facebook/Atiku Abubakar

Gbọingbọin lawọn ọmọ orilẹede Naijiria wa lẹyin ile ẹjọ giga julọ, oludije fun ipo aarẹ labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu PDP ninu ibo gbogbogbo to lọ, Atiku Abubakar lo sọri lẹyin ti ileẹjọ yẹ aga mọ oludije ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina nipinlẹ Bayelsa nidii, David Lyon.

Ọla ọjọ Ẹti ló yẹ kí wọ́n búra fún David Lyon gẹgẹ bi gomina tuntun ipinlẹ Bayelsa ki ileẹjọ to ga julo to paṣẹ pe olùdíje PDP Sẹnẹtọ Douye Dirini ni yoo gori aga gomina ipinlẹ naa.

Ileẹjọ ni igbakeji oludije ẹgbẹ osélu APC Biobarakuma Degi-Eremienyo to lo ayederu iwe ẹri lo ṣakoba fun Ọgbẹni Lyon ti ajọ INEC kọkọ kede pe oun lo jawe olubori.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ rẹ, Atiku ni pẹlu idunnu loun fi gba iroyin idajọ ile ẹjọ to ga julọ pe oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo ṣe gomina ipinlẹ Bayelsa bayii.

''Awọn adajọ tun ti fihan pe ọwọ awọn araalu ni agbara wa, amọ ileẹjọ to ga julọ ni lati maa da ẹjọ lai ṣegbe lẹyin ẹnikan,'' Atiku lo sọ bẹẹ.

Image copyright @others

Atiku rọ awọn eeyan ipinlẹ Bayelsa lati gba alafia laaye, lẹyin idajọ ileẹjọ to ga julọ l'Ọjọbọ.

Àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ yẹgi mọ́ Olùdíje gómìnà APC ní Bayelsa nídìí

Ni kete ti ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria da ibo to gbe David Lyon nu ni ipinlẹ Bayelse, awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni fi eroungba wọn lede lori idajọ ọhun.

Kola Ologbondiyan to jẹ alukoro apapọ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa ku ori ire lori idajọ ọhun.

Comrade Mayor ni tirẹ sọpe "Ogo fun Ọlọrun... Awọn eeyan ipinlẹ Bayelsa ti gba ohun to jẹ tiwọn."

Ni ti Efadi Gold9ja, o sọ pe oun fẹran idajọ naa, ati pe inu oun dun lati wa laye lasiko ti iru idajọ bẹẹ waye.

Bi inu awọn kan ṣe n dun ti wọn si faramọ idajọ naa, awọn mii n sọ pe idajọ ọhun kii ṣe idajọ ododo.

Benin Finest ni ẹgbẹ PDP ni ẹgbẹ ti ko wulo julọ ninu gbogbo oṣelu to wa ni Naijiria.

Image copyright @AfricResource

Taitos Special ni ojoro ni idajọ to da ibo David Lyon nu, bi bẹ kọ, o yẹ ki ile ẹjọ kan naa da ẹtọ Ihedioha to ji gbe lọ ni ipinlẹ Imo.

Ẹ wo awọn awọn ohunn mii ti awọn eeyan n sọ.

Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?

Bayelsa Supreme Court: Ìgbìmọ̀ adájọ́ ẹlẹ́ni márùn-ún ní ayédèrú ìwé ẹ̀rí ni olùdíje APC fi dìbò

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti kede pe ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa ti wọgile ibo to gbe oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC wọle nipinlẹ Bayelsa.

Oludije naa, David Lyon ni ajọ eleto idibo INEC kede pe oun lo jawe olubori ninu ibo gomina to kọja, ti oun ati igbakeji rk si ti n mura feto imura.

Amọ igbimọ oludajọ ẹlẹni marun, ti adajọ Mary Odili ko sodi, ti pasẹ fun ajọ Inec lati gba iwe ẹri moyege kuro lọwọ oludije APC naa.

O fikun pe ko se iwe ẹri tuntun fun oludije fẹgbẹ PDP, pe oun lo jawe olubori ninu ibo ọhun.

Ileẹjọ giga naa ni ki ajọ eleto idibo Inec fun oludije ẹgbẹ oselu to ni ibo to pọ sikeji, to si tun ni ibo to tan iyẹ kaakiri ipinlẹ naa lasiko ibo gomina to kọja.

O ni ki wọn fun wọn ni iwe ẹri moyege ibo tuntun, to si foju han ẹgbẹ oselu PDP lo ba awọn akawe yii mu

Image copyright Degi-Eremienyo

Adajọ Ejembi Ekwo, to ka idajọ naa sita lorukọ awọn adajọ yoku pasẹ bẹẹ, lẹyin to kede pe oludije fẹgbẹ oselu APC ninu ibo gomina naa, Degi-Eremienyo, ko lẹtọ lati soju ẹgbẹ oselu naa.

A ranti pe ileeẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja ti fofin de Degi-Eremienyo lati dije fun ipo gomina ọhun tori pe ayederu iwe ẹru lo gbe kalẹ fun ajọ eleto idibo naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Radio Day: Àwọn òṣìṣẹ́ rédíò ní àwọn ń pa ìsòro àwọn mọ́ra ni láti mú inú aráàlú dùn

Ileẹjẹ naa ni idajọ yii ti ko oludije ati igbakeji rẹ papọ nitori tikẹẹti alapapọ lati dije ni awọn mejeeji ni, ti wọn si jọ gbegba ibo papọ lọjọ kẹrindinlogun osu Kọkanla ọdun 2019 to kọja.