Cabinet reshuffle: Sajid Javid kọ̀wé fipò Káńsélọ̀ sílẹ̀, Rishi Sunak gba ipò rẹ̀

Sajid Javid Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọn ti fi Rishi Sunak rọpo Sajid Javid lẹyin to kọwe fipo silẹ

Ọkan pataki lara awọn adari ijọba ilẹ Gẹẹsi, Sajid Javid ti kọwe fipo silẹ, lẹyin ti olori ijọba Boris Johnson ṣe atunto igbimọ ijọba orilẹ-ede naa.

Ikọwe fiposilẹ yii lo waye lẹyin ti ilẹ Gẹẹsi yapa kuro lara ajọ Iṣọkan ilẹ Yuroopu.

Ọgbẹni Javid kọ lati fọwọ osi juwe ile fun awọn to n ba ṣeṣẹ ni bo ṣe sọ pe kii ṣe ohun dara lati ṣe.

Oṣu keje ọdun 2019 ni Boris Johnson yan Sajid sipo lẹyin to gori alefa gẹgẹ bi olori ijọba ilẹ Gẹẹsi.

Ki Sajid to kọwe fiposilẹ, awọn ahesọ kan ti n waye pe họwuhọwu wa laari rẹ̀ ati ọgbẹni Dominic Cummings, to jẹ olubadamọran pataki si Boris Johnson.

Ni bayii, wọn ti fi Rishi Sunak rọpo rẹ.

Image copyright @htTweets
Àkọlé àwòrán Sunak ni minisita fun eto ilegbe tẹlẹ ko to ri igbega sipo akọwe iṣura orilẹ-ede Gẹẹsi.

Rishi Sunak jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji, o si kawe ni Winchester College ati Fasiti Oxford lẹyin naa lo da ileeṣẹ aladani kan silẹ.

Sunak di minisita fun eto ilegbe lọdun 2018 ko to ri igbega sipo akọwe iṣura orilẹ-ede Gẹẹsi.