Operation Amotekun: A ó da ọlọ́pàá agbègbè àti Amotekun papọ̀ - Ọ̀gá ọlọ́pàá Naijiria

Amotekun Image copyright @ekitistategov

Ọga agba ajọ ọlọpaa orilẹ-ede Naijira, Muhammed Adamu ti sọ pe ọlọpaa agbegbe tí ijọba apapọ n gbero rẹ yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu ikọ Amotekun ilẹ Yoruba.

Adamu lo sọ ọrọ yii nibi ijiroro kan to waye pẹlu awọn gomina ilkẹ Yoruba nilu Eko lori agbekalẹ ọlọpaa agbegbe.

O sọ fun awọn akọroyin pe "Ipade keji niyi ti a maa ṣe pẹlu awọn gomina naa lori agbekalẹ ikọ Amotekun."

Adamu ṣalaye pe "Gbogbo ipinlẹ lo ni eto abo ti wọn lati koju iwa ọdaran, ikọ Amotekun ko si yatọ si iru agbekalẹ bẹẹ.

O ni ajọ ọlọpaa ati awọn gomina naa ti fẹnuko lati sọ ọlọpaa agbegeb ati Amotekun di ọkan ṣoṣo ki eto abo ilu lee jẹ lati ọwọ awọn ara ilu.

Image copyright @followlasg
Àkọlé àwòrán Adamu sọ pe ajọ ọlọpaa yoo ṣatilẹyin fun awọn eeyan lati ri pe agbegbe wọn wa ni alafia

Ọga agba ajọ ọlọpaa naa tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria yoo lọwọ si igbanisiṣẹ ati idanilẹkọ awọn eeyan ti yoo ṣeṣẹ gẹgẹ bi ikọ Amotekun.

Adamu sọ pe eto abo gbọdọ bẹre lati ọdọ awọn ara ilu, lẹyin naa lo rọ awọn eeyan lati fọwọsowọpọ gbogun ti iwa ibajẹ.

Adamu pari ọrọ rẹ pe ajọ ọlọpaa yoo ṣatilẹyin fun awọn eeyan lati ri pe agbegbe wọn wa ni alafia.