Oyo Land Revocation: Ajimobi gbé Makinde lọ ilé ẹjọ́ lórí ilẹ̀ rẹ̀ tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé

Abiola Ajimobi àti Seyi Makinde

Gomina ana nipinlẹ Oyo, Sẹnatọ Abiola Ajimobi ti gbe Gomina Seyi Makinde ati awọn eeyan mii ninu ijọba rẹ lọ ile ẹjọ, lẹyin ti wọn gbẹsẹle ilẹ rẹ nilu Ibadan.

Ṣaaju ni iroyin kan jade pe, ijọba ipinlẹ Oyo gbẹsẹ le awọn ilẹ kan lagbegbe Agodi ati Jericho, nilu Ibadan nitori awọn idi kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọ kẹwa oṣu keji ọdun 2020 ni aṣẹ jade pe, ki wọn gbẹsẹ le awọn ilẹ ọhun nitori pe lilo rẹ lodi si anfani awọn ara ilu ati ijọba.

Atẹjade kan lati ọwọ agbẹnusọ Gomina Makinde, Taiwo Adisa ṣalaye pe, gomina kan tẹlẹ nipinlẹ ọhun lo ra ilẹ naa, ti gomina to ṣaaju rẹ si gbẹsẹ le e, to si fi ilẹ naa fun oniṣowo kan ni Ibadan.

Image copyright Others

O tẹsiwaju pe, oniṣowo ọhun ṣe iforukọsilẹ ilẹ naa pẹlu ileeṣẹ ijọba to n ṣamojuto ọrọ ilẹ, to si sọ pe oun ti bun gomina ana miran nilẹ ọhun.

Ṣugbọn o ni ninu iwe kootu kan to tẹ awọn akọroyin lọwọ, ni wọn ti fiwe pe Gomina Makinde, kọmiṣọna fun ọrọ ilẹ ati ilegbe, to fi mọ adajọ agba ipinlẹ Oyo, lati wa sọ tẹnu wọn lori bi ọrọ ọhun ṣe jẹ.

Iwe ipẹjọ ọhun to jade lọjọ kejila oṣu Keji ọdun 2020 sọ pe, iwa ẹtanu ni bi wọn ṣe gbẹsẹ le ilẹ naa jẹ ati inunibini.

Ile ẹjọ naa tun dena ijọba Oyo lati gbe igbesẹ kankan lori ọrọ ilẹ ọhun, titi ti igbẹjọ yoo fi bẹrẹ.