Amotekun: Ìjọba Eko kéde pé òun ní ẹ̀ṣọ́ aláàbò tẹ́lẹ̀, òun kò sí ní yí orúkọ rẹ̀ padá sí Amotekun

Amotekun Image copyright facebook/Amotekun

Kọmiṣọna feto iroyin ni ipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso ti sọ pe ipinlẹ naa ko fa sẹyin ninu eto aabo rara, ki awọn gomina ilẹ Yoruba to daba agbekalẹ ikọ alabo Amotekun.

Omotoso ni ti eto Amotekun ba fẹsẹ mulẹ tan, ẹṣọ alabo ipinlẹ Eko ko ni yi orukọ rẹ pada lati "Neighborhood watch" to n lo fun aabo agbegbe pada si Amotekun, nitori iṣẹ kan naa ni wọn n ṣe.

Omotoso, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ kede pe lẹyin agbekalẹ Neighbourhood Watch, lawọn ipinlẹ yoku bii Oyo, Ogun ati Ondo gbe abadofin Ametekun lọ si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ wọn.

Ni ti pe ipinlẹ Eko n fa sẹyin lati gbe abadofin Amotekun lọ si ile igbimọ aṣofin rẹ, o ṣalaye pe "Ati ni ofin to ju ti Amotekun lọ, tile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti fọwọsi ṣaaju akoko yii, orukọ nikan lo yatọ."

"Ipinlẹ Eko ti ni nnkan to jọ mọ nnkan ti wọn sọ yẹn tipẹtipẹ, ko to di akoko yii."

Kọmiṣọna naa ṣalaye pe, eto aabo ayika ki n ṣe nnkan tuntun nipinlẹ Eko, nitori ipinlẹ ọhun ti ni ẹsọ alabo ayika to dantọ tẹlẹ.

Image copyright @EKITISTATEGOV

Omotoso ṣalaye pe, ọga agba fun ileesẹ ọlọpaa ti ṣalaye fun awọn gomina ilẹ Yoruba pe, eto Amotekun kii ṣe eto gbogbo ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ṣugbọn ki olukuluku ṣe amojuto eto abo wọn lọtọtọ.

Omotoso wa pari ọrọ rẹ pe "orukọ ti wọn n jẹ naa ni mo ro pe wọn maa jẹ lọ, a ko le yi orukọ wọn pada. Nnkan to ba yẹ ni ṣiṣe lati daabo bo awọn eeyan wa, la o ṣe."