Bayelsa: Douye Diri di gómìnà Bayelsa lẹ́yìn ìbúrawọlé, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde kóńlé ó gbélé

Douye Diri Image copyright Facebook/Seyi Makinde

Adajọ agba nipinlẹ Bayelsa, Kate Abiri ti ṣe ibura fun oludije ipo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP, Douye Diri gẹgẹ bi gomina tuntun ipinlẹ naa.

Ni irọle ọjọ Ẹti ọjọ kẹrinla oṣu lkeji ni ibura naa waye nile iṣẹ ijọba nilu Yenagoa tii ṣe olu ilu ipinlẹ Bayelsa.

Bakan naa ni adajọ agba ipinlẹ Bayelsa ṣe ibura fun Sẹnẹtọ fun Lawrence Ewhrudjakpo gẹgẹ bi igbakeji gomina tuntun ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwẹ, ile iṣẹ ti kede ofin konile o gbele ti yoo maa bẹrẹ lati irọlẹ di idaji ọjọ keji nipinlẹ Bayelsa lẹyin tawọn olufẹhonu ati awọn janduku kọlu ile gomina tuntun fun ipinlẹ naa, Douye Diri ti wọn si ba nkan jẹ.

Ọga agba ọlọpaa nipinlẹ naa, Uche Anozia lo ṣe ikede naa fawọn akọroyin lọjọ Ẹti.

Image copyright Twitter/nigeria police

Ọgbẹni Anozia to ṣe ikede naa nibi tawọn ọga ajọ eleto aabo miran naa ti wa nijoko ṣalaye pe alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla oṣu Keji yii naa ni eto konle o gbele ọhun yoo bẹrẹ.

Ọga ọlọpaa naa ṣe ikilọ pe ẹnikẹni to ba ta felefele laarin aago mẹjọ alẹ si aago mẹfa aarọ yoo foju wina ofin.

Niṣe ni ile iṣẹ ijọba ipinlẹ Bayelsa kun fọfọ nigba ti ọga ọlọpaa n ṣe ikede naa.

Àwọn jàndùkú kọlu ilé gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa tuntun, wọ́n ba nkan jẹ́

Iroyin kan to tẹwa lọwọ ni pe awọn olufẹhonu ati awọn janduku kọlu ile gomina tuntun fun ipinlẹ Bayelsa, Douye Diri ti wọn si ba nkan jẹ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin The Punch ṣe jabọ iroyin, awọn janduku naa ba awọn ọkọ kan ti wọn gbe sinu ọgba ile naa jẹ, ati abala kan lara ile naa.

Image copyright Punchng

Eyi waye lẹyin ti ajọ INEC fun Diri ni iwe ẹri moyege gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Bayelsa.

Image copyright Punchng

Ọsan ọjọ Ẹti ni ajọ eleto idibo Nigeria, Inec ti fun oludije gomina fẹgbẹ oselu PDP, Sẹnatọ Douye Diri ati igbakeji ni iwe ẹri moyege ibo gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Bayelsa.

Image copyright Punchng

Eyi waye lọjọ lẹyin ipade ti ajọ Inec ṣe nilu Abuja lati jiroro lori idajọ ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria to waye l'Ọjọbọ.

Image copyright Twitter/OfficialPDPNIg
Àkọlé àwòrán Ajọ INEc ti fun oludije PDP, Douye Diri ni iwe ẹri moyege

Ile ẹjọ naa wọgile ibo to gbe oludijẹ ẹgbẹ oselu APC wọle nipinlẹ Bayelsa, to si yẹ ki wọn bura fun lonii.

Eyi lo si fidi rẹ mulẹ pe gbogbo igbiyanju oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ APC, David Lyon lati sebura wọle bii gomina ipinlẹ Bayelsa l'oni, ọjọ Ẹti lo ti ja si pabo.

Image copyright Others

Ṣaaju ni ajọ eleto idibo naa ni oun ti setan lati gbe iwe ẹ́ri moyege ibo fun oludije ẹgbẹ oselu PDP, Senator Douye Diri ati igbakeji rẹ, Lawrence Ewhruojakpo, gẹgẹ bi ileẹjọ ti paa lasẹ.

Lati Ọjọbọ ti ile ẹjọ si ti dajọ ni omi nu ti n kọ awọn eniyan ipinlẹ Bayelsa lori taa ni gomina ipinlẹ Bayelsa ti wọn yoo bura fun loni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionValentine: Ọkùnrin ní kí obìnrin má fún àwọn ní àwọ̀tẹ́lẹ̀ mọ́ bíi ẹ̀bùn ọjọ́ olólùfẹ́

Idi ni pe ẹgbẹ oselu APC ati PDP ti n tutọ si ara wọn loju lori ohun ti idajọ ileẹjọ naa sọ, ti ko si tii foju han, ẹni ti wọn yoo bura fun bii gomina ni Bayelsa.

Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nilu Abuja, alaga ẹgbẹ oselu APC, Adams Oshiomole leri leka, to si n tọ ilẹ la pe ko si ẹnikẹni ti wọn yoo bura fun bii gomina ni Bayelsa lonii.

Image copyright David Lyon

Oshiomole ni "kii se bonkẹlẹ mọ pe ile ẹjọ to ga julọ ti dajọ pe wọn ko lee bura fun David Lyon, bẹẹ si ni ẹni to ni ibo to pọ julọ sikeji ni ki wọn bura fun. Eyi tumọ si pe lati ọla lọ, ko ni si ijọba kankan mọ ni Bayelsa."

O fikun pe oludije fẹgbẹ PDP ko ni ida mẹta ibo to yẹ ninu eto idibo gomina ọhun, ti ọwọja ibo rẹ ko si tan ka ida mẹta ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ naa.

Image copyright Adams Oshiomole

Amọ agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan ni ofo lasan ni ihalẹ Oshiomole nitori ofuutu, fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ni.

Ẹgbẹ oselu PDP wa n fewe ọmọ mọ Oshiomole leti lati ta kete si ipinlẹ Bayelsa nitori igbinyanju rẹ lati da rogbodiyan silẹ nipinlẹ naa, ti kuna.

Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin pe ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa ti yẹ aga gomina mọ David Ylon, tii se oludije gomina fẹgbẹ APC nidi, ẹni ti ajọ Inec kede pe oun lo moke ninu ibo gomina to waye nipinlẹ naa losu Kọkanla ọdun 2019.

Idi ni pe ẹni to jẹ igbakeji Lyon naa, Biobarakuma Degi-Eremienyo, ko ayederu iwe ẹri kalẹ fun ajọ eleto idibo, to si mu ki awọn Lyon ati igbakeji rẹ naa kuna lati lee de ipo gomina.

Oni, ọjọ Ẹti lo yẹ ki wọn bura fun Lyon ati igbakeji rẹ naa amọ nibayii, ti ileẹjọ ti kede pe ki wọn gba iwe ẹri moyege ti ajọ Inec fun, ki wọn si kọ iwe ẹri miran fun oludije ẹgbẹ oselu PDP, taa wa ni wọn yoo bura fun bii gomina Bayelsa lonii.

Koda, lọwọ aarọ ana ni Lyon ti n se igbaradi fun bi wọn yoo se bura fun bii gomina lonii, ti ko si mọ pe riro ni teniyan, sise ni ti Ọlọrun, bẹẹ ni igun ijọba ẹgbẹ oselu PDP to n dari Bayelsa gan ti setan lati fa ibi ti akoso de duro le Lyon lọwọ.