Buhari visits Borno: Garba Shehu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ló jáde kí ààrẹ káábọ̀, wọ́n ló ṣeun ṣeun

Are Buhari

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ alátakò ló ràn àwọn èèyàn láti pariwo lé ààrẹ Buhari lori.

Ilé iṣẹ́ ààrẹ orilẹ̀èdè Naijiria ti fẹ̀sùn kan àwọn ẹgbẹ alatako pé, awọn lo san owo láti gba àwọn to kígbe le ààrẹ Muhammadu Buhari lori lasiko ìrìnàjò rẹ̀ lọ si ìpínlẹ̀ Borno lọ́jọ́ru ni.

Oluranlọ́wọ́ pàtàkì àgbà lori igbòhun sáfẹ́fẹ́ fún ààrẹ Buhari Garba Shehu, lo fẹ́sun náà kan lásìkò to n ba BBC sọ̀rọ̀.

Awọn olùgbé ìlú Maiduguri ti ṣe olúùlú ìpínlẹ̀ Borno pe bo ọkọ ààrẹ lọ́jọ́ru, ti wọn si kígbe ni ìlòdì si ìrìnàjò ààrẹ Buhari lóri ìṣekupani ti àwọn ọlọsa ṣe si àwọn arinrinajo ọgbọ̀n ni Borno.

Shehu ni "Mo wa lára àwọn to rin ìrìnàjo náà láti pápákọ ofurufu titi de ààfin Shehu Borno, àwọn ènìyàn jáde ti wọ́n ki ààrẹ kaabọ, wọn ni o ṣeun fun àbẹ̀wò naa."

Oríṣun àwòrán, Others

"Sùgbọ́n lójìji ni àwọn kan de ti wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ni kígbe pe 'A ò fẹ́, A ò fẹ́'

O ní o ṣeeṣe ki àwọn ọlọṣelu ẹgbẹ́ alátako kó àwọn ènìyàn jọ, ki wọ́n si fún wọ́n ni owó láti lọ yẹ̀yẹ́ ààrẹ Buhari"

Gẹ́gẹ́ bi Garba Shehu ṣe sọ, ẹnikẹni to ba ya fọ́nran ibi ti wọ́n ti n pariwo le ààrẹ, to sì tún pin ká lóri ayélujara kò ṣe e láti ràn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Borno lọ́wọ́, bi wọ́n ṣe jẹ́ ẹni ti gbogbo ènìyàn mọ gẹ́gẹ́ bi ìlú to maa n gbà alejò.

Àkọlé fídíò,

Valentine: Ọkùnrin ní kí obìnrin má fún àwọn ní àwọ̀tẹ́lẹ̀ mọ́ bíi ẹ̀bùn ọjọ́ olólùfẹ́

O ní ìjọba to n bẹ lóde ti ṣe gudugudu meje, yaya mẹfa láti koju Boko Haram, ti àwọn si ti tun ń pinnu láti yi ìlànà àtẹyinwá pada.