Sunday Igboho: Ọ̀pọ̀ abulẹ̀-ṣowó tó ta ilẹ̀ fún wa ti kú, àwọn ọmọ wọn ló ńí ká tún ilẹ̀ rà

Sunday Igboho Image copyright Instagram/Sunday Igboho

Awọn olugbe agbegbe Soka niluu Ibadan ṣe alaye fun ikọ BBC Yoruba wi pe, lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin ni wahala awọn ọmọ onilẹ ti n waye ni lemọlemọ ni adugbo naa ki o to di wi pe Sunday Igboho da sii lọdun yii.Ọpọlọpọ awọn ogiri ile ni wọn ṣe ami si wi pe, awọn ọmọ onilẹ ti gbẹsẹ lee pẹlu atilẹyin ile ẹjọ giga, lasiko ti ikọ BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe naa lowurọ Ọjọ Ẹti.

Awọn olugbe agbegbe naa to ba wa sọrọ labẹ aṣọ ṣalaye pe, pupọ ninu awọn abulẹṣowo to ta ilẹ fun awọn lo ti di oloogbe.

Awọn ọmọ awọn oloogbe naa lo wa yirapada di ọmọ onilẹ to n ṣoro bi agbọn, pẹlu ẹsun wi pe ọna aitọ ni wọn gba ra awọn ilẹ naa.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa, ti o ni ki a fi orukọ bo oun laṣiri ṣe alaye wi pe, igba mẹfa ọtọọtọ ni awọn ọmọ onilẹ ti lọ gba aṣẹ ile ẹjọ lati gbẹsẹ le awọn ilẹ ti awọn eeyan ti kọle si lori, ni agbegbe Soka.

O tẹsiwaju wi pe, "ohun to maa n gbẹyin ọrọ lọpọ igba ni ki awọn ọmọ onilẹ naa gba owo ibọbẹ lẹyin idunkukulaja wọn, ṣugbọn airi owo gba lọdun yii lo da gbọmi si omo o to silẹ."

"Awọn ọmọ onilẹ naa ko ọlọpaa lẹyin, t'oun ti aṣẹ ile ẹjọ gẹgẹ bi iṣe wọn lọsẹ yii. ki ilumọọka ajafẹtọmọniyan Sunday Igboho to gbẹna woju wọn.Lati ọjọ Isẹgun ti isẹlẹ naa ti waye, awọn olugbe agbegbe naa ṣe alaye wi pe, awọn ko tun tii ri ọmọ onilẹ kankan mọ ni agbegbe Soka niluu Ibadan.