Coronavirus: Orílẹ̀-èdè Egypt ti ṣe àkọsílẹ̀ ẹni àkọ́kọ́ tó ní ààrùn Coronavirus

Awọn eleto ilera

Ẹka eto ilera lorilẹede Egypt ti kede pe eeyan kan ti niaarun coronavirus lorilẹede Egypt.

Eyi ni igba akọkọ ti aarun naa yoo mu ẹnikankan nilẹ Afirika lati igba to ti bẹrẹ niluu Wuhan lorilẹede China.

Awọn alaṣẹ ẹka eto ilera lorilẹede Egypt ko sọ bo ya ọmọ orilẹede Egypt lẹni to naa tabi ajeji ni.

Amọ wọn ti fi to ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO, l'eti, bẹẹ ni wọn si fi ẹni naa pamọ si ibi kan fun itọju ati ayẹwo siwaju sii.

Orilẹ-ede Egypt ni orilẹ-ede kejidinlogun ti aarun naa ti tan kalẹ de bayii, ohun si ni akọkọ nilẹ Afirika.

O le ni ẹgbẹfa eeyan to ti di oloogbe lẹyin ti wọn ko aarun coronavirus. Bakan naa ni eniyan to le ni ẹgbẹrun mẹrinlelọgọta ni ayẹwo fihan pe wọn ti ni aarun naa kaakiri agbaye.